Bayelsa Election: Ẹgbẹ́ òṣèlú APC kọ̀ láti kópa nínú ìdìbò, PDP jáwé olúborí

Apoti idibo ni bAYELSA

Oríṣun àwòrán, Bayelsa State Min of Information and Orientation

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló jáwé olúbori nínú ìdìbò alága ìjọba ìbílẹ̀ àti kánsẹ́lọ tó wáye lọ́jọ́ sátide ọjọ kẹwàá oṣù kẹ́jọ ọdun 2019 .

Ẹgbẹ́ alátakò to pọ̀ jùlọ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà People's Democratic Party (PDP) ti pegedé nínú ìdìbò alága kansu àti ti kánsẹlọ̀ tó wáyé lásìkò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ to wáyé ní ìpínlẹ̀ Bayelsa ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹ́jọ ọdun 2019.

Ìròyìn to tẹ BBC lọ́wọ́ sọ pé àwọn ènìyàn péréte lo jáde lọ si ibi idibò náà, sùgbọ́n ìrọwọ́ rọsẹ̀ ni wáye

Àkọlé fídíò, Aláráǹbàraà! Ẹ wo àrà tí ''Ayo the Creator'' ń fi sinimá dá

Alága, elétò ìdìbò ìpínlẹ̀ Bayelsa, ọjọgbọ́n Remember Ogbe sàlàyé fún BBC pé eto ìdìbò náà wáyé ni ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́jọ tó gbé ìpínlẹ̀ Bayelsa ró, ó sì jẹ ìdìbò to lọ ni ìrọwọ́rọsẹ̀ júlọ ní ìpínlẹ̀ Bayelsa."Ìdìbò ti a lé fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìdá ọgọ́ta nínú àwọn olùdibò jáde wá àànú Ọlọ́run ni a fi ṣe ìdìbò náà ti kò si sí ìjà tàbi kí ẹnikẹ́ni kú, gbogbo àyíká wà ni dídákẹ́ rọ́rọ́, a dupẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run"

Ọ̀jọ̀gbọ́n Ogbe sọ pé mẹ́rìnlélógójì nínú mọ́kànléláàdọ́run àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú to forukọ sílẹ̀ lókópa nínú ìdìbò náà, sùgbọ́n ẹgbẹ́ òṣèlu tó ń bẹ lóri àléfaà All Progressives Congress (APC) wà lára àwọn ẹgbk òṣèlú tí kò kópa nínú ìdìbò náà

Ìgbìyànjú BBC láti bá alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC Jotan Amos sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára, ìdí ti wọn kò fi kópa nínú ìdìbò náà, sùgban kò gbé aago rẹ̀.

Ikede Esi idibo ijoba ibilẹ Bayelsa

Oríṣun àwòrán, Alambo Datonye

Àkọlé àwòrán, Ikede Esi idibo ijoba ibilẹ Bayelsa