Orílẹ̀-èdè Togo gbe òfin tuntun silẹ̀ lórí ìwọ́de ìfẹ̀hónu hàn

olufehonu han
Àkọlé àwòrán, Orílẹ̀-èdè Togo: Kò sí ààye ìwọ́de ìfẹ̀hónu han mọ́ lórílẹ̀-èdè yìí

Ìlé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀-èdè Togo, tí jan òfin tuntun tó ni kò si ààyè fún ìwọ́de ìfẹ̀hónú han lọ́ntẹ.

Èyí wáyé lẹ́yìn ti ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ alátakò ń ṣe ìwọ́de lórilẹ̀-èdè náà, òfín tuntun yìí jẹ ọ̀nà láti dẹ́kun ìwọ́de wọn.

Sùgbọ́n ìjọba ní awọn ṣe òfin náà láti mú kíí ààbò tó péye wà lóri ìlú, bótilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ alátakò ríí gẹ́gẹ́ ọ̀nà láti mú adíkù bá ọ̀rọ̀ ti ará ìlú ń jà sí pé ìdílé kan ṣoṣo ló ti ń ṣe ìjọba láti ọdun 1967.

Àkọlé fídíò, Kayeefi: Facebook ni Wolii Arole Jesu fi tàn an wọ agbo, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó

Lábẹ́ òfin túntún yìí, kò ni sí ààyè fú ẹnikẹ́ni láti ṣe ìwóde lóju pópó, láàrín ìlú tàbí ní agbègbè ilé ìjọba.

Ìwọ̀de kò lè wáyé sáájú aago mọ́kanla àárọ̀ tàbí kọja ààgo mẹ́fa ní ìrọ̀lẹ́, gẹ́gẹ́ bó ti ń ṣẹlẹ̀ sáájú àsíkò yìí, ìjọba Togo lé fòfinde wọ́n pátápátá nítori àwọn ìdí yìí.

Àkọlé fídíò, Yollywood: Sinimá Ajé Ọjà tún so Fathia àti Saheed Balogun pọ̀ nínú Sinimá
Àkọlé fídíò, Asa Trokosi nibi ti ọmọde ti n jiyan ẹsẹ mọlẹbi rẹ , wọpọ ni Ghana, Togo ati Benin.

Ìròyìn fi kún pé òfin náà wáye nítori pé àwọn agbásùmọmi tí n dúnkokó mọ́ ìjọba.

Atúnṣe ti wọ́n ṣe si òfin orílẹ̀-èdè náà fún ààrẹ Faure Gnassingbé wà lórí oye titi di ọdun 2030, èyí ti ó túmọ sí pé tó ba di àsìkò náà ìdíle Gnassingbé ti wà ní ìjọba fún ọdún mẹ́tà lé láàdọ́ta.