Èsí ìdánwò WAEC: Ìdá 53 nínú ọgọ́rún akẹ́ẹ̀kọ́bìnrin fakọyọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n risi idanwo awọn akẹẹkọ jade Girama ni agbeegbe Iwọ- oorun Afirika, WAEC ti fi esi idanwo asekagba(SSCE) ti ọdun 2018 si ita.
Ajọ WAEC naa kede pe awọn akẹẹkọ to le ni miliọnu kan aabọ lo joko ṣe idanwo naa, ti awọn akẹẹkọ to to 786, 016 (ida 49.98 to din diẹ ni ilaji awọn to ṣee) si pegede ninu idanwo Ẹkọ Isiro (Mathematics ) ati Ẹkọ Ede Gẹẹsi(English Language).
Awọn to se idanwo WAEC naa ti ko si jẹ WAEC ni owo le ri esi idanwo naa ni oju opo ayelujara ti WAEC : www.waecdirect.org.
Adari ajọ WAEC ni orilẹede naijiria, Olu Adenipekun sọ fun awọn akọroyin wi pe awọn to pegede ninu idanwo WAEC naa ni ipinlẹ Ekodin pẹlu ida mẹwa.
Olanipekun ni iye awọn to pegede ninu esi idanwo naa ni Ọkunrin jẹ 389, 655 (ida 47.32) ti Obinrin si jẹ 396, 361 ( ida 52.92 ).

Ọga agba ajọ WAEC naa wa fi kun wi pe iwe ẹri esi idanwo WAEC naa yoo wa fun awọn eniyan lati gba ni Osu mẹta si asiko yi.









