Bat: Kìí ṣe ènìyàn nìkàn ló ń ṣe òfin ìyàsọ́tọ̀ lásìkò àìsàn ẹranko kan rèé tó ń ṣe bẹ́ẹ̀

Ǹjẹ ẹmọ̀ pé kìí ṣe ènìyàn nìkan lo ń ṣe ètò ìyaraẹni sọ́tọ̀ lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe àìsàn?
Sáájú àsìkò yìí tí àjàkálẹ̀ ààrùn kan bá ti bẹ́ sílẹ̀, tó sì jẹ́ pé ààrùn náà sábà máa n ràn láti ọ̀dọ̀ ẹnìkàn si ẹlòmíràn, àwọn àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ ààrùn jákèjádò àgbàyé a máa ṣètò àwọn ibi ìyàsọ́tọ̀ fún àwọn tó ba ni ààrùn náà.
Ẹ̀wẹ̀, ìwádìí kan ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé iṣe ènìyàn ni ìṣe ẹranko, ẹranko kan náà wà tó máa n ṣe ètò ìyàsọ́tọ̀ lásìkò tí wọ́n ba wà lórí àkéte àìsàn.
- Àwọn ọ̀dọ́ ya bo ààfin Akire láti jí oríadé gbé
- Agbára wa kò ká àrùn Covid-19 mọ́ - Ìjọba ilẹ̀ Amẹrika
- Taa gan ló ni Lekki Toll gate láàrin aráàlú àti Asiwaju Tinubu?
- Iyabo Ojo gé okùn àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú olóṣèlú nínú ẹgbẹ́ APC ati PDP
- Mo ti tọrọ aṣọ àti yẹtí etí rí, kí n tó leè ṣe àwo orin - Tope Alabi
Àbí, ẹyín ni ẹrànko kìí ṣe àìsàn? Ẹranko à máa ṣe àìsàn wọn si ń gba ìtọjú láàrìn ara wọn pẹ̀lú.
Nínú àtẹ̀jáde ìwádìí kan ti fásìtì Oxford ṣe lo ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ti àwọn àdán bá wà lórí àkéte àìsan wọ́n máa n sètò ìyàsọ́tọ kí ààrùn náà ma baa tànkálẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí náà ṣe sọ, àwọn onímọ̀ tí kọ́kọ́ gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò nínú yàrá àyẹ̀wò, kí wọn to lọ ṣe ìwádìí láàrín àwọn àdàn náà.
Ìwádìí ni ní kété tí àdán bá ti rii pé òun ṣe àìsàn ní yóò ti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn tó kù kìí àìsàn náà má ba tànkálẹ̀.
Nínú ìwàdìí míràn ni ìwádìí ti fihan pé àwọn ẹrànko míràn a maa ya ara wọn sọ́tọ̀ fúnra wọ́n, sùgbọ́n nígbà míràn ẹ̀wẹ̀ àwọn ni wọ́n yóò pa èyíkéyìí tó bá ni àìsàn náà kí o ma ba ko ran ẹlòmíràn.












