Worldcup2018; Spain fọwọ́ òsì júwe ilè fún akọ́nimọ̀ọ́gbá wọn

Julen Lopetegui

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Spain kò fìdí rẹmi nínú gbogbo ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí wọ́n gbá nígbà tí Julen Lopetegui fi jẹ́ Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ náà

Akọnimọọgba fẹgbẹ agbabọọlu Spain, Julen Lopetegui, ti padanu iṣẹ rẹ ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ akọkọ wọn pẹlu Portugal, ninu ife ẹyẹ agbaye Russia 2018.

Ajọ to n ri si ere bọọlu nilẹ naa, RFEF, da Lopetegui duro, lẹyin ti ikọ Real Madrid kede rẹ gẹgẹ bii akọnimọọgba ti yoo rọ́pọ̀ Zinedine Zidane, to fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ajọ RFEF sọ pe, awọn gbe igbesẹ naa nitori Lopetegui ti bẹrẹ idunadura pẹlu Real Madrid ti ajọ naa ko si gbọ nkankan.

Àkọlé fídíò, Super Eagles: Akojọpọ aworan asọ fun ife ẹyẹ agbaye

Ife ẹyẹ agbaye Russia 2018 bẹrẹ ni Ọjọbọ.

Olori ajọ RFEF, Luis Rubiales, sọ pe, igbesẹ naa ko ni pa ẹgbẹ agbabọọlu Spain lara nigbati wọn ba koju Portugal lọjọ Ẹti.

Lopetegui di akọnimọọgba Spain l'ọdun 2016 lẹyin ti akọnimọọgba orilẹede naa tẹlẹ̀, Vicente del Bosque fẹyin ti.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amin iyasọtọ kan
Àkọlé fídíò, 'IBB da Abiola lẹ́yìn tó búra pẹ̀lú Quran'