Trump: Ìpàdé èmi àti Trump so èso rere

Donald Trump àti Kim Jong-un

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ààrẹ orílẹ́èdè America ṣe ìpàdé fún ìgbà àkọ́kọ́ pẹ̀lú olórí orílẹ́èdè North Korea

Aarẹ orilẹede America, Donald Trump sọ pe, ijiroro oun pẹlu olori orilẹede North, Korea Kim Jong-un yọri si rere.

Lara awọn adehun ti awọn olori orilẹede mejeeji naa fọwọ si ni pe, Jong-un yoo palẹ awọn nkan ogun ija oloro mọ́ nilẹ ní Korea.

Aarẹ Trump fi kun ọrọ rẹ pe, oun yoo da iṣẹ awọn ọmọ ogun ilẹ America duro ni orilẹede South Korea.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ipade naa ni akọkọ iru rẹ laarin Aarẹ orilẹede America to wa lori oye pẹlu olori orilẹede North Korea, to si so eso rere fun awọn mejeeji.

Trump ati Jong-un ṣe ileri nibi ipade naa lati fọwọ ṣowọpọ lori ibaṣepo titun.

Orilẹede America si fọwọ sọya wipe ohun yoo ṣeto aabo to daju fun orilẹede North Korea