World Cup 2026: Canada, US àti Mexico ni yóò gbàlejò ife ẹ̀yẹ àgbáyé 2026

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìpàdé àpérò ìkejìdínláàdọ́rin tó ń wáyé ní orílẹ̀èdè Mexico ti yan Amerika, Canada àti Mexico láti gbàlejò ife ẹ̀yẹ àgbáyé ti ọdún 2026.
Orílẹ̀èdè Morocco ti ń fàá pẹ̀lú àpapọ̀ Amerika, Canada àti Mexico èyí tí wọ́n jùmọ̀ pè ní 'United 2026' láti gbàlejò ìdíje ti ọdún 2026.
Ànfàní tí ilẹ̀ àríwá Áfíríkà ní tún gòkè síi lọ́sẹ̀ yìí láti jẹ́ olùgbàlejò ìdíje ńlá náà lágbàyé lẹ́yìn tí orílẹ̀èdè mẹ́rin ní erékúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà gbà wípé àwọn fọ ọwọ́ kúrò nínú ìdìbò àsekágbá.
Sùgbọ́n ti àpapọ̀ orílẹ̀èdè mẹ́ta 'United 2026' ló dùn un gbọ́ jù nítorí pápá bọ́ọ̀lù àwòmáleèlọ́ wọn, àwọn yàrá ìgbàlejò àti ọ̀nà tó tẹ́ lọ bí ẹní tó fi mọ́ èrè owó tí yòó mú wá.








