Bàbá mi kò lórúkọ́ àmọ́ èmi ti fòpin sí óṣèlú ‘ta a ni baba rẹ’ nipinlẹ Ọyọ - Ṣeyi Makinde

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde Facebook

Gomina ipinle Ọyọ, Onimọ-ẹrọ Ṣeyi Makinde ti sọ pe ori oun ni opin ti de ba oṣelu ‘ta a ni baba rẹ’ nipinlẹ Ọyọ to maa n ṣẹlẹ tẹlẹ .

Makinde sọ pe oun ti fopin si i pẹlu ijawe olubori oun gẹgẹ bii gomina Ọyọ nigba meji lai lẹni kan afi Oluwa.

Ọjọru, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹrin ọdun 2024 yii ni Gomina Makinde sọrọ naa nibi eto awọn akẹkọọ kan ti Agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin Ọyọ, Ọnarebu Debọ Adedoyin gbe kalẹ, n’Ibadan.

Ṣeyi Makinde ṣalaye pe igba kan ti wa ri nipinlẹ Ọyọ, to jẹ ta a ni baba tiẹ nilẹ yii ni wọn fi n se oṣelu.

Bàba mi ò gbajúmọ̀ l’Ọyọọ́ táwọn èèyàn fi yàn mi ládarí - Makinde

Gẹgẹ bi Gomina Ṣeyi Makinde ṣe wi, ’’baba to bi mi ki i ṣe gbajumọ nipinlẹ Ọyọ tawọn eeyan fi dibo fun mi.

‘’Bẹẹ igba kan ti wa nilẹ yii ri to jẹ ti baba eeyan ko ba ti lorukọ, ọmọ rẹ o le rọwọ mu ninu oṣẹlu.

’’ Emi ti mo wa nibi, mo ti ri apẹẹrẹ igba to jẹ ‘ta a ni baba ẹ nilẹ yii’ lo kun inu oṣelu, ṣugbọn emi ti fopin si i.

’’Bi baba mi ṣe jẹ ẹni ti ko lorukọ to, awọn eeyan fun mi lanfaani lati dari wọn’’

Nigba to n gba awọn akẹkọọ naa nimọran fun ọjọ ọla wọn, Makinde sọ pe awọn ọdọ Naijiria gbọdọ maa kopa ninu oṣelu nitori ọjọ iwaju.

‘’Ẹyin naa tẹ ẹ jẹ akẹkọọ lasiko yii, agbara ṣi wa fun yin pẹlu akoko. Bi ẹ ba lo o daadaa, ẹ le jẹ adari.

‘’Ẹ maa ronu ibi giga. Bi ẹ ba wo itan Naijiria, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn pere ni Ọgagun Yakubu Gowon to fi dari ilu.

‘’Ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (39) ni Ọgagun Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti fẹyinti ninu iṣẹ ologun.

‘’Ẹ ma ṣe ro pe ẹ kere ju lati dari lẹni ọdun mọkandinlọgbọn tabi ọgbọn,asiko to daa ju lati bẹrẹ gan-an niyẹn’’

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde Facebook

Àwọn ìgbà tí Mákindé gbìyànjú láti di gómìnà Ọyọ́

Ẹ o ranti pe ọdun 2007 ni Ṣeyi Makinde kọkọ gbiyanju ati di gomina ipinlẹ Ọyọ, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ANPP, ṣugbọn o padanu nigba naa.

Ni 2015, o tun gbiyanju labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Social Democratic party (SDP), ṣugbọn ipo kẹta lo mu.

Ni 2019 lọsan so didun fun Makinde ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, nigba to fẹyin Adebayọ Adelabu to dije ninu APC nalẹ.

Ṣeyi Makinde tun wọle ẹẹkeji ninu idibo 2023, eyi ti saa naa n lọ lọwọlọwọ.