Àwọn òmùwẹ̀ ṣàwárí òkú èèyàn méjì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi wó afaára lulẹ̀ ní Baltimore

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọ́n ti ṣàwárí òkú ènìyàn méjì kan yọ nínú ọkọ̀ ńlá kan tó wà lábẹ́ omi níbi tí afárá Baltimore ti já lulẹ̀.
Àwọn òṣìṣẹ́ mẹ́fà tó ń ṣiṣẹ́ lórí afárá náà ló wà lórí rẹ̀ lásìkò tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kan fi kọlùú, tí gbogbo wọn sì kó sínú omi.
Wọn ṣàwárí àwọn méjì nínú àwọn òṣìṣẹ́ náà lọ́jọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí wáyé, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wá àwọn yòókù.
Èròńgbà ni pé àwọn yòókù náà yóò ti jẹ́ Ọlọ́run nípè.
Mẹ́rin nínú àwọn mẹ́fà tí èròńgbà wà pé wọ́n ti bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ ni wọ́n ti fi orúkọ wọn léde.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Maryland lọ́jọ́rú ní Alejandro Hernandez Fuentes, ẹni ọdún márùndínlógójì àti Dorian Ronial Castillo Cabrera, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni wọ́n ti rí òkú wọn yọ nínú ọkọ̀ lábẹ́ omi.
Àmọ́ àwọn òmùwẹ̀ kò lè tẹ̀síwájú láti máa wá àwọn èèyàn lábẹ́ omi mọ látàrí àwọn nǹkan tó wà lábẹ́ odò náà gẹ́gẹ́ bí àlàyé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá.
Àwọn méjì míì tí wọ́n ń wá, tí wọ́n sì lérò pé wọ́n ti jáde láyé ni wọ́n gbé orúkọ wọn jáde gẹ́gẹ́ bíi Miguel Luna àti Maynor Suazo Sandoval.
Iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèrè Mexico ti ṣáájú sọ pé àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè òun méjì ló wà nínú ìkọlù náà àti pé wọ́n rò pé àwọn méjéèjì ti jáde láyé.
Ọ̀kan nínú wọn ni Fuentes tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí òkú rẹ̀ yìí, tí wọ́n sì ti dóòlà ẹ̀mí ẹ ìkejì ṣáájú.
Àwọn aláṣẹ ní ọ̀kan lára àwọn tó ń gbà ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí wọ́n dóòlà ẹ̀mí rẹ̀ nínú odò náà ló ti kúrò nílé ìwòsàn báyìí.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí ni àwọn tó kọ́kọ́ fẹ́ dóòlà ẹ̀mí àwọn òṣìṣẹ́ mẹ́fà náà ló nínú odò Patapsco lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.
Lásìkò tí àwọn àwọn òṣìṣẹ́ náà ń ṣiṣẹ́ láti di kòtò tó wà lórí afárá náà ni ọkọ̀ ojú omi ńlá kan kọlu afárá ọ̀hún tí àwọn òṣìṣẹ́ náà sì já sínú odò.
Àwọn aláṣẹ ṣèlérí láti wá òkú àwọn òṣìṣẹ́ náà fún àwọn ènìyàn wọn nítorí wọ́n rò pé gbogbo wọn ti máa dágbére fáyé nítorí ọ̀pọ̀ wákàtí tí wọ́n ti lò nínú omi.
Gómìnà Maryland, Wes Moore sọ fún àwọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́rú pé gbogbo nǹkan tó bá wà ni àwọn fi máa wá òkú àwọn ènìyàn náà.
Àmọ́ ọ̀gá àgbà ẹ̀ṣọ́ ojú omi, Peter Gauthier ní ṣíṣe àwárí àwọn òkú náà kò rọrùn rárá.
Ó ní omi tó tutù gidi, tí àwọn pàǹtí láti ara afárá tó já lulẹ̀ náà wà nínú rẹ̀ ni àwọn òmùwẹ̀ ti ń wá àwọn ènìyàn náà.
Gautier ní ọkọ̀ ojú omi tó kọlu afárá náà ló gbé epo tó lé ní mílíọ̀nù kan àbọ̀ gálọ́ọ̀nù àti pé àwọn nǹkan tó lè ṣàkóbá fún ara wà lára àwọn ẹrù tí ọkọ̀ ojú omi náà gbé.
Jennifer Homendy, alága àjọ tó ń rí sí ààbò ètò ìrìnnà ojú omi ní àwọn kọ̀ǹténà tí àwọn nǹkan tó lè ṣàkóbá fún èèyàn wà nínú rẹ̀ ni àwọn ti ń gbìyànjú láti yọ.
Iléeṣẹ́ ètò ààbò ojú omi Amẹ́ríkà ní àwọn fẹ́ lo irinṣẹ́ ńlá láti fi yọ àwọn irin afárá náà tó já sínú omi?
Sri Lanka ni ọkọ̀ ojú omi náà ń lọ kó tó pàdánù ìjánu rẹ̀ lójijì, tó sì pè fún ìrànlọ́wọ́ kó tó kọlu afárá Baltimore.
Ìwádìí ọkọ̀ ojú omi ṣàfihàn pé kò ju ìṣẹ́jú kan lọ tí ọkọ̀ náà pàdánù ìjánu rẹ̀ ló kọlu afárá náà.
Àwọn aláṣẹ ní bí afárá náà ṣe já lé ní ipa lára ètò ọrọ̀ ajé Amẹ́ríkà.
Moore ní ó ṣeéṣe kí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ iṣẹ́ fara gbá nínú ìkọlù náà tó sì pè ní àjálù àgbáyé.
Ó ní ètò ọrọ̀ ajé Amẹ́ríkà àti ti àgbáyé ló gbára lé ibùdókọ̀ náà.
Ó wòye pé ọkọ̀ ojú omi tí iye rẹ̀ tó bílíọ̀nù ọgọ́rin dọ́là ni wọ́n gbé gba ibẹ̀ ní ọdún tó kọjá.
Paul Wiedefeld, akọ̀wé iléeṣẹ́ ètò ìrìnnà Maryland tẹmpẹlẹmọ pé ṣíṣe àtúnṣe afárá náà le má wáyé ní kíákíá àmọ́ ó ṣèlérí pé àwọn ń ṣiṣẹ́ láti ri pé wọ́n wá òmíràn fún un láti lè jẹ́ kí ibùdókọ̀ ojú omi náà lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láìpẹ́.
Àwọn onímọ̀ ní ó ṣeéṣe kí wọ́n máa pàdánù mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dógún dọ́là lójúmọ́ títí tí wọ́n fi máa tún ọ̀nà mìíràn ṣí.
Sẹ́nétọ̀ Maryland, Ben Cardin ní òun ní ìgbàgbọ́ pé orílẹ̀ èdè máa pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò láti fi bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe afárá míì láìpẹ́.














