Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá fa ẹ̀kún omi, bá dúkíà jẹ́, bí NIMET ṣe ní ọjọ́ mẹ́ta ni ojó alágbára yóò fi rọ̀ yíká Nàíjíríà

Oríṣun àwòrán, Others
Ọjọ manigbagbe, ọjọ buruku Eṣu gbomi mu ni Ọjọru ọjọ kẹta oṣu Keje ọdun 2024 nipinlẹ Eko ati kaakiri awọn ipinlẹ Yoruba, lẹyin ti ojo arọrọọda kan to ṣokunfa ẹkun omi ṣọṣẹ ti o ṣi ṣakoba fawọn araalu.
Bi awada bi ere ni ojo ọhun bẹrẹ ni idaji Ọjọru lai mọ pe ojo naa yoo rọ ti ilẹ yoo fi ṣu ni.
Awọn olugbe lawọn ipinlẹ ti ojo naa ti rọ, ti wọn n lọ sẹnu iṣẹ laarọ kutu, ni ojo arọrọọda yii kọkọ ni ipa to lagbara lori wọn.
Ni ati aarọ kutu Ọjọru yii ni ọwọ ojo naa ti le, ti o ṣi fa ẹkun omi eyi to bo titi mọlẹ awọn agbegbe to wa yika ilẹ Yoruba, paapaa kaakiri ilu Eko.
Ọpọ lo pada sile tori ẹkun omi, nigba tawọn mii pẹ de ibi iṣẹ l'Ọjọru
Ọpọ awọn oṣiṣẹ ti ọfiisi wọn wa ni erekusu ilu Eko papaa julọ lawọn agbegbe Victoria Island, Ikoyi ati Lekki ni wọn pẹ de ibi iṣẹ wọn ni Ọjọru lẹyin ti ẹkun omi ko jẹ ki wọn rọna kọja loju popo.
Fidio kan tawọn eeyan fi lede lori itagun ayelujara X ṣafihan bi omi ṣe pọ loju ọna mọrosẹ Ikorodu si erekusu ilu Eko ti ọpọ awakọ ko si le rin mọ tori ẹkun omi yii.
Ẹkun omi yii naa ni lo jẹ ki ọkọ tawọn eeyan le wọn lọ sibi iṣẹ wọn lati ri, ti ero ṣi pọ biba lawọn ibudokọ kaakiri ilu Eko.
Fidio mii to tun jẹyọ lori itakun ayelujara X tun ṣe afihan bi opopona Alapere, Ogudu, Olopomeji lọ si erekusu kun fun omi eyi to jẹ ko nira fawọn awakọ lati wa ọkọ wọn kọja ninu rẹ.
Ẹkun omi yii fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ loju popo naa eyi to mu ki ọpọ awọn oṣiṣẹ pẹ de ibi iṣẹ wọn.

Oríṣun àwòrán, Others

Oríṣun àwòrán, Others
Ìjọba ipinlẹ Eko tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ aráàlú lẹ́yìn tí ẹ̀kún ṣọṣẹ́ l’Eko l’Ọ́jọ́rú
Ijọba ipinlẹ Eko ti tọrọ aforijin lọwọ araalu lẹyin ti ẹkun omi ṣakoba fun ọpọ eeyan l’Ọjọru ni ipinlẹ naa.
Ẹgbẹlẹgbẹ eeyan ni ko le de ibi iṣẹ wọn lasiko to yẹ lẹyin ti arọrọọda ojo ana ṣokunfa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ loju popo kaakiri ilu Eko.
Nigba to n sọrọ lori ileeṣẹ tẹlifisan Channels l’Ọjọbọ, kọmiṣọnna ọrọ ayika ati ohun alumọni ilu omi, Tokunbo Wahab ni ‘’ijọba ipinlẹ Eko tọrọ aforojin lọwọ awọn eeyan ipinlẹ lori inira ti ẹkun omi Ọjọru ti le ṣe fun wọn.
Ọpọ olugbe ilu Eko lo ti fi aidunnu wọn lori itakun ayelujara pe ijọba ko ṣiṣẹ rẹ bii iṣẹ lo jẹ ki ojo maa fa ẹkun omi lọdọọdun eyi to ṣakoba fun araalu.
Amọ, Ọgbẹni Wahab sọ pe kii ṣe ẹbi ijọba ni ẹkun omi to waye ni Ọjọru.
Kọmiṣọnna ṣalaye wi pe ayipada oju ọjọ lo ṣokunfa ẹkun omi to ṣakoba fawọn araalu l’Ọjọru.
O ni ṣaaju ki ojo yii to rọ ni ijọba ti sọ fawọn akọṣẹmọṣẹ lati ṣe ohun ti wọn ba le ṣe ti ẹkun omi ko fi ni ṣakoba fawọn eeyan.

Ojo arọrọọda Ọjọru fa ẹkun omi ni ipinlẹ Oyo
Kii ipinlẹ Eko nikan ni ojo arọrọọda Ọjọru ti fa ẹkun omi to ṣakoba fawọn araalu.
Ọwọja ojo yii de ipinlẹ Oyo bakan naa, ni ṣe ni omi gori oju popo kaakiri ilu Ibadan.
Ọpọ ni ko ri ọkọ wọ lọ si ibi iṣẹ oojọ wọn tori ọpọ awakọ ni ko le rin loju popo tori ẹkun omi to ti gba titi.

Ojo arọrọọda ṣakoba fawọn eeyan ipinlẹ Ogun
Ọpọ agbegbe bii Sango-Ota, Alagbado, Atan, Oju-ore ati Lusada ni ipinlẹ Ogun ni ojo arọrọọda Ọjọru ti ṣọṣẹ bakan naa.
Ọpọ awọn agbegbe yii lo sọ pe awọn to n da ilẹ soju ibi ti omi n gbe kọja lo jẹ ki awọn koto idaminu yii di, eyi to ṣi fa ẹkun omi.
Olugbe agbegbe Atan-Ota kan, Abayomi Rufai, sọ pe oun ti padanu dukia to to ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu naira latari ẹkun omi Ọjọru.
Victoria Ojelana ti oun n gbe lagbegbe Oregun niluu Ijebu Ode sọ pe gbogbo ile oun ni omi ya wọ to fi mọ ile awọn aladugbo oun naa.
Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ogun ti fawọn eeyan ipinlẹ naa lọka balẹ wi pe ko si ewu lẹyin ẹkun omi Ọjọru.
Kọmiṣọnna ọrọ ayika ni ipinlẹ naa, Ola Oresanya lo fidi ọrọ yii mulẹ.
O ni ajọ Nimet to n ri si ọrọ oju ọjọ ti kilọ ṣaaju pe ojo arọrọọda yoo rọ eyi ti yoo si fa ẹkun omi.
Amọ, to ba ti ojo naa ba da tan, ẹkun omi naa yoo pada lọ.

Ojo Ọjọru jẹ kawọn oṣiṣẹ pẹ de ibi iṣẹ wọn l’Ondo
Ojo nla rọ nipinlẹ Ondo bakan na ni Ọjọru, o ṣi ṣakoba fawọn eeyan ipinlẹ naa lẹnu iṣẹ wọn.
Iroyin to tẹ wa lọwọ fidi rẹ mulẹ pe ọpọ oṣiṣẹ lo pẹ ki wọn to de ibi iṣẹ wọn latari ojo nla to rọ naa.
Bakan naa ni a gbọ wi pe ọpọ awọn ontaja ni ko le ṣi ṣọọbu wọn ti ilẹ naa ṣu.
Amọ, a o gbọ wi pe ojo ọhun fa omiyale agbara ya ṣọọbu bi ti ipinlẹ Eko.
















