Wo báàgì tó ń lo ìtànṣán oòrùn, ó tún ní páàdì nǹkan oṣù fáwọn ọmọdébìnrin
Bi ọjọ ṣe n gori ọjọ ni imọ n gori imọ, njẹ ẹyin ti ri baagi to n lo itanṣan oorun ri?
Ẹ ma laagun jinna, awọn kan ti ṣe baagi alaranbara to n lo itanṣan oorun lorilẹede Naijiria.
Ina kan wa lara baagi ọhun to jẹ pe oorun lo n ro o lagbara.
Koda, awọn ohun elo iranṣọ tun wa ninu baagi ọhun.
Awọn ike to ṣee sọ di nnkan mi-in tawọn eeyan o lo mọ, ni wọn yi pada fi ṣe baagi ọhun lati bori iṣoro airowo ra paadi laarin awọn ọdọmọbinrin
Bẹẹ ni baagi yii tun ni iwe pelebe to n kọ ni nipa imọtoto lasiko nnkan oṣu.
Gbogbo ẹ lo ṣe rẹgi lai si wahala kan.
Eleyii yatọ si baagi ileewe lasan ti wọn n lo tẹlẹ.
Awọn ike to ṣee sọ di nnkan mi-in tawọn eeyan o lo mọ, ni wọn yi pada ti wọn fi ṣe baagi ọhun lati bori iṣoro airowo ra paadi laarin awọn ọdọmọbinrin orilẹede Uganda.
Awọn ohun eelo ti wọn fi ṣe baagi yii ko ni i jẹ ki omi le ba a jẹ.
Jamila Mayanja, to jẹ oludasilẹ ajọ to n ri si ijafafa awọn ọmọbinrin Uganda ṣalaye pe ''ojo maa n rọ pupọ ni Kampala nigba mi-in.
Awọn ọmọbinrin maa n rin ọna to jin lati ile wọn de ileewe.
Bi wọn ba n lọ nigba mi-in lasiko nnkan oṣu wọn ti ojo si n rọ, ohun ti wọn n lo fi ṣe nnkan oṣu naa yoo rẹ, ṣe ẹ mọ pe awọn paadi to ṣee tun lo la n fun wọn lati maa fi ṣe e.''
Iriri Jamila nigba ni kekere lo mu un ronu lati ṣe baagi yii
Iriri Jamila nigba ewe rẹ gan an lo mu ki o ronu lati ṣe baagi yii.
Jamila sọ pe ẹkọ to peye lori imọtoto fawọn ọmọbinrin ni lasiko to n ṣe nnkan oṣu ṣe pataki.
Bayii ni o ṣe ṣawari awọn ọmọbinrin ti wọn nilo iranlọwọ yii, pẹlu atilẹyin awọn olori adugbo ati awọn olukọ.
O si pin baagi naa fun wọn lọfẹẹ lai gbowo.
Jamila ni eroja to n lo oorun si i baagi yii, to le ro ina lagbara.
Yoo tun fun wọn ni ina ti wọn le lo lati fi kawe nigba ti ko ba sina.
Jamila ni idaji kutu lawọn mi-in ninu wọn si ti maa n jade, igi si pọ lawọn oju ọna.
O ni fun idi eyi, awọn mi-in ninu wọn maa n lo ina to wa lara baagi yii lati fi da aabo bo ara wọn.
Jamila ni pinpin baagi fawọn ọmọdebinrin to nilo rẹ mu inu oun dun gan-an.














