Àríyànjiyàn lórí aṣọ ìnáwó láàrin ọ̀rẹ́ méjì ní Ilorin yọrí sí ikú ọ̀kan lára wọn

Oloogbe Usman

Oríṣun àwòrán, Adebayo Hammed

Ọrọ di bo lọ ya mi ni ilu Ilọrin olu ilu ipinlẹ Kwara lasiko ti ija ajaku akata bẹ silẹ laarin awọn ọrẹ meji kan, ti ọkan lara wọn si di eero ọrun.

Iṣẹlẹ naa lo si ti sọ awọn olugbe agbegbe Isalẹ Koto Ọja Gbọọrọ ni Ilọrin sinu ibẹru bojo.

Ọgbẹni Adebayọ Hammed to jẹ aburo baba oloogbe Usman sọ pe ọjọ Ẹti to kọja, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta, 2024, ni iṣẹlẹ na sẹlẹ.

O ṣe alaye pe aigbọraẹniye lo sẹlẹ laarin Usman ati ọrẹ rẹ Omotosho Jimoh, to si yọri si iku Usman.

Ọgbẹni Adebayọ sọ fun BBC pe, oogun ibilẹ ni Omotosho fi lu ọrẹ rẹ, to si ku. Amọ, a ko le fidi eyi mulẹ.

“Jimoh lo kọkọ n bu Usman pe otete lo aṣọ inawo ti wọn mu gbo, eyi to bi Usman ninu pe ṣe Jimoh lo ra aṣọ fun ohun ni, to ba ṣe wu oun l’oun ṣe le lo aṣọ.

Awọn mejeeji ko sọ ju bayii lọ ti ọrọ fi di ija rẹpẹtẹ.”

Ẹgbọn oloogbe ṣalaye pe awọn to wa nibẹ la wọn nija, amọ lẹyin isẹju diẹ ti wọn pari ija fun wọn, ni Jimoh ṣa deede wọle, to si mu oogun jade, eyi to fi gba Usman.

O ni loju ẹsẹ ni Usman bẹrẹ si ni laagun, ti wọn si gbe lọ sile iwosan nibi ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe, Usman ti ku.

Agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejire Toun Adeyẹmi, sọ pe Ọgbẹni Adebayọ Hammed lo fi ọrọ naa to ileesẹ ọlọpaa l’eti.

Ejirẹ Adeyẹmi sọ pe afurasi naa Jimoh Omotosho ti salọ, amọ iwadii ṣi n lọ lọwọ lori Iṣẹlẹ na.

Ofikun pe mọlẹbi oloogbe kọ lati yọnda oku rẹfun iwadii, wọn ni awọn o lọ sin ni ilana ẹṣin islam.