Àwọn agbófinró dúró wámúwámú lódò Yemoja n'llọrin, ọdún Ìṣẹ̀ṣe kò wáyé níbẹ̀

Ọkẹ aimọye awọn ọlọpaa, sifu difẹnsi, awọn ọmọ ologun, atawọn ọtẹlẹmuyẹ mi-in ni wọn duro nibi odo Iyemọja, to wa ni Oko-Olówó, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, nibi ti awọn ẹlẹsin Iṣẹṣe ti ṣaaju ni awọn fẹ ti ṣayẹyẹ ọdun Iṣẹṣe lagbaye tẹlẹ ki wọn to wọgile akojọpọ ọhun.
Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, CP Ẹbunoluwarotimi Adelesi, lo ṣaaju awọn ẹsọ alaabo yooku lọ si odo Iyemọja, to wa lagbegbe Oko-Olówó, lati ri i daju pe wahala ko sẹlẹ laaarin awọn onisẹse ati awọn musulumi ni Ilọrin gẹgẹ bi wọn ṣe ti n leri sira wọn tẹlẹ.
Tẹ o ba gbagbe lati bii oṣu kan sẹyin ni awuyewuye ti n waye laarin awọn Alfa atawọn ẹlẹsin Iṣẹṣe niluu Ilorin latari ayajọ ọdun iṣẹṣe agbaye tawọn oniṣẹṣe fẹ ṣe lodo Iyemọja ọhun.
Awọn eniyan iliu Ilorin fariga pe awọn ko ni gba ki awọn ajoji wa maa sọdun ti wọn ko mọ mọ Ilorin, ti awọn onisẹse naa si sọ pe awọn yoo sọdun dandan.
Nigba ti awuyewuye naa lagbara ni Kọmiṣanna ọlọpaa Kwara, Ẹbunoluwarotimi Adelesi pe awọn ẹlẹsin mejeeji lati bawọn pari aawọn naa.


O ni ki alaafia le jọba ni Kwara gẹgẹ bi wọn ṣe mọ-ọn-mọ sẹyin, ki awọn oniṣẹṣe lọ sọdun Iṣẹṣe nipinlẹ mi-in gẹgẹ bi wọn ṣe maa n ṣe tẹlẹ.
Nigba to di owurọ ọjọ Aiku, ogunjọ oṣu Kẹjọ ti ọdun Iṣẹṣe yoo waye, lẹyin ti ọpọlọpọ awọn ẹsọ alaabo ti duro wamu sibi odo ọhun lati fi poro ofin gbe ẹnikẹni to ba tapa sofin, atawọn Alfa ati oniṣẹṣe ko sẹni to yọju si ibi odo naa.
Nigba ti Kọmiṣọna ọlọpaa n ba akọroyin BBC sọrọ, o ni bi awọn Alfa atawọn oniṣẹṣe ṣe n leri si ara wọn ni awọn ṣe ko awọn ẹṣọ aabo lọ si ibi odo naa.
O ni bi alafia yoo ṣe jọba ni ipinlẹ Kwara ni o jẹ ileeṣẹ ọlọpaa logun ati pe aabo ẹmi ati dukia ṣe pataki si awọn jọjọ.
"Lati ọjọ Abamẹta ni awọn ọlọpaa ti wa ni agbegbe yii lati ri pe ẹnikẹni ko fa wahala tabi jagidijagan kankan.”
O ni lotitọ gbogbo eniyan lo ni ẹtọ labẹ ofin lati sin ẹsin to ba wu u ṣugbọn nitori aabo ara ilu lawọn ṣe gba awon oniṣẹṣe ni iyanju wi pe kiwon ma ṣe ọdun naa, wọn si gba si awọn lẹnu.
Awọn agbofinro naa duro lati orita Oko-Olowo titi de odo Yemoja naa lati ri wi pe ko si ẹni to tasẹ agẹrẹ si ofin.














