Oyetola di Mínísítà fétò ìrìnnà, Wike ni Mínísítà fún FCT bí Tinubu ṣe kéde ipò àwọn mínísítà tuntun

Oríṣun àwòrán, Facebook
Ààrẹ Bola Tinubu ti kéde ipò àwọn mínísítà tí yóò máa bá ṣiṣẹ́.
Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola ni yóò máa rí sí ètò ìrìnnà nígbà tí gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike ni mínísítà tuntun fún Abuja.
Bákan náà ni oludìjé sípò gómìnà Oyo lẹ́gbẹ́ òṣèlú Accord Party níbi ètò ìdìbò tó kọjá, Adebayo Adelabu ni yóò máa ṣàkóso ẹ̀ka ohun àmúṣagbára.
Ní alẹ́ ọjọ́rú ni ìkéde náà jáde láti ọwọ́ olùbádámọ̀ràn ààrẹ lórí ìròyìn, Ajuri Ngalele.
Omi tuntun ru díẹ̀ lọtẹ yìí lásìkò Ààrẹ Tinubu torí bí àfikún ṣe wà sí àwọn ipò tó ti wà tẹ́lẹ̀ ni akanpọ dé bá àwọn ipò míì.
Torí náà, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn orúkọ tó jáde rèé àti ipò tí wọ́n gbà gẹ́lẹ́ pẹ̀lú àwọn orúkọ ipò náà bí Ààrẹ ṣe pé wọ́n:
Orúkọ àti ipò àwọn Minisita tuntun
- Mínísítà fétò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ọgbọ́n inú àti ètò ọrọ̀ ajé ìgbàlódé - Bosun Tijani
- Mínísítà kejì fọ́rọ̀ àyíká - Ishak Salako
- Mínísítà fétò ìsúná àti àkóso ètò ọrọ̀ ajé - Wale Edun
- Mínísítà fétò ojú omi àti ọrọ̀ ajé inú omi - Gboyega Oyetola
- Mínísítà fọ́rọ̀ ohun àmúṣagbára - Adebayo Adelabu
- Mínísítà kejì fétò ìlera àti àmójútó àwùjọ - Tunji Alausa
- Mínísítà fétò ìdàgbàsókè ohun àlùmọ́ọ́nì ilẹ̀ - Dele Alake
- Mínísítà fọ́rọ̀ ìgbáfẹ́ - Lola Ade-John
- Mínísítà fétò ìrìnnà - Saidu A. Alkali
- Mínísítà fétò ìdókoòwò - Doris Anite
- Mínísítà fọ́rọ̀ ọgbọ́n inú, sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ - Uche Nnaji
- Mínísítà kejì fọ́rọ̀ òṣìṣẹ́ àti ìgbanisíṣẹ́ - Nkiruka Onyejeocha
- Mínísítà fọ́rọ̀ àwọn obìnrin - Uju Kennedy
- Mínísítà fún iṣẹ́ òde - David Umahi
- Mínísítà fétò ìrìnnà òfurufú - Festus Keyamo
- Mínísítà fún ẹkùn Niger Delta - Abubakar Momoh
- Mínísítà fétò pípa òṣì rẹ́ - Betta Edu
- Mínísítà kejì fọ́rọ̀ afẹ́fẹ́ gáàsì - Ekperikpe Ekpo
- Mínísítà kejì fọ́rọ̀ epo bẹntiróòlù - Heineken Lokpobiri
- Mínísítà fétò eré ìdárayá - John Enoh
- Mínísítà fún olú ìlú Nàìjíríà - Nyesom Wike
- Mínísítà fọ́rọ̀ àṣà àti ètò ọrọ̀ ajé àtinúdá - Hannatu Musawa
- Mínísítà fétò ààbò - Mohammed Badaru
- Mínísítà kejì fétò ààbò - Bello Matawalle
- Mínísítà kejì fétò ẹ̀kọ́ - Yusuf T. Sunumu
- Mínísítà fọ́rọ̀ ilé gbígbé àti ìdàgbàsókè ìlú - Ahmed M. Dangiwa
- Mínísítà kejì fọ́rọ̀ ilé gbígbé àti ìdàgbàsókè ìlú - Abdullah T. Gwarzo
- Mínísítà fétò ìsúná àti ètò ọrọ̀ ajé - Atiku Bagudu
- Mínísítà kejì fọ́rọ̀ olú ìlú Nàìjíríà - Mairiga Mahmud
- Mínísítà kejì fọ́rọ̀ omi àti ìmọ́tótó - Bello M. Goronyo
- Mínísítà fétò ọ̀gbìn àti àmójútó oúnjẹ - Abubakar Kyari
- Mínísítà fétò ẹ̀kọ́ - Tahir Maman
- Mínísítà fọ́rọ̀ abẹ́lé - Bunmi Tunji
- Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè - Yusuf M. Tuggar
- Mínísítà fétò ìlera àmójútó àwùjọ - Ali Pate
- Mínísítà fọ́rọ̀ àwọn Ọlọ́pàá - Ibrahim Geidam
- Mínísítà fún ìdàgbàsókè Steel - Shuaibu A. Audu
- Mínísítà kejì fún ìdàgbàsókè Steel - Maigari Ahmadu
- Mínísítà fétò ìròyìn àti ìlanilọ́yẹ̀ - Muhammed Idris
- Agbẹjọ́rò àgbà àti Mínísítà fétò ìdájọ́ - Lateef Fagbemi
- Mínísítà fọ́rọ̀ òṣìṣẹ́ àti ìgbanisíṣẹ́ - Simon Lalong
- Mínísítà kejì fọ́rọ̀ àwọn ọlọ́pàá - Imaan Sulaiman-Ibrahim
- Mínísítà fàwọn àkànṣe iṣẹ́ - Zephaniah Jisalo
- Mínísítà fọ́rọ̀ omi àti ìmọ́tótó - Joseph Utsev
- Mínísítà fétò ọ̀gbìn àti ọ̀rọ̀ oúnjẹ Aliyu Sabi Abdullahi
- Mínísítà fétò àyíká








