Akẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan mẹ́wàá dèrò iléèwòsàn lẹ́yìn tí wọ́n fa gáàsì olóró símú

Oríṣun àwòrán, The Polytechnic, Ibadan
Ko din ni akẹkọọ mẹwaa lati ileewe Gbogboniṣe ipinlẹ Oyo, (The Ibadan Polytechnic) ti wọn balẹ sileewosan lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanla oṣu Keji ọdun 2025, lẹyin ti wọn fa gaasi oloro kan simu.
Ohun ti a gbọ ni pe lẹyin ti awọn ọmọ naa ti wọn jẹ akẹkọọ ẹka ti wọn ti n kọ nipa ayẹwo ẹjẹ; 'Department of Science Laboratory Technology' (SLT), pari idanrawo ranpẹ ni wọn lugbadi afẹfẹ oloro naa.
Gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ yii ṣoju wọn ṣe ṣalaye, wọn ni awọn akẹkọọ meji kan ni wọn n ba ara wọn ja lẹyin idanrawo ranpẹ ti wọn ṣe.
Nibi ti wọn ti n gbiyanju lati la wọn ni wọn ti ni ọkan ninu awọn to n ja naa gbe eroja gaasi to le sé èémí mọ eeyan lara jade, to si fin in sinu afẹfẹ.
Eyi lo mu ọpọ awọn akẹkọọ naa ṣubu lulẹ nigba ti wọn fa kinni ọhun simu, awọn mi-in si daku lọ rangbọdan.
Kia ni wọn sare gbe wọn lọ sileewosan ẹkọṣẹ iṣegun Oyinbo (UCH) n'Ibadan, ati ti ijọba ipinlẹ Oyo; Ring Road State Hospital.
Ohun ti wọn fa simu naa ko ti i di mimọ lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.
ìpínlẹ̀ Oyo gbé ìgbésẹ̀
Lọgan ti ipe de etigbọọ ijọba ipinlẹ Oyo nipa iṣẹlẹ naa ni Kọmiṣanna eto ilera Oyo, Dokita Oluwaserimi Ajetunmobi, ko ikọ lẹyin lọ si awọn ileewosan ti awọn akẹkọọ ọhun ti n gba itọju.
Dokita Ajetunmobi fidi ẹ mulẹ, pe ara awọn akẹkọọ naa ti balẹ, wọn si ti n gba itọju to yẹ.
O rọ awọn alaṣẹ ileewe Poly Ibadan lati wadii iṣẹlẹ yii finni-finni , ki wọn si ri i pe awọn to lọwọ nibẹ koju ofin.
Bakan naa ni Kọmiṣanna sọ pe o ṣe pataki kawọn alaṣẹ ileewe maa ṣe idanilẹkọọ fun awọn ọmọ ileewe wọn.
Ajetunmobi sọ pe eyi yoo jẹ ki wọn dẹkun iwa to le da omi alaafia ilu ru, ati iwa jagidijagan.














