Kò sí ìlú ní ìpínlẹ̀ Osun tí mi ò ti máa ṣe iṣẹ́ àkànṣe níbẹ̀ - Adeleke

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/FACEBOOK
Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke ti ní àyípadà ti bá ìpínlẹ̀ Osun lẹ́yìn oṣù méjì tí òun gba àkóso ìpínlẹ̀ náà.
Gómìnà Adeleke sọ èyí níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìròyìn The Punch.
Ó ní sísan owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ déédéé àti mímu ìgbáyégbádùn àwọn òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì ní ọ̀kúnkkúndùn jẹ́ àfójúsùn ìjọba òun láti ìgbà tí òun ti wà lórí ipò láti ọdún méjì sẹ́yìn.
"Ipò táwọn òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì wà nígbà tí mo dé kò da rárá, ọ̀pọ̀ wọn ló ń dágbére fáyé nítorí ìjọba tó wà nípò tẹ́lẹ̀ kàn pawọ́n tì.
"Èyí ló mú mi gbé ètò Imole Free Medical Care Programme kalẹ̀ fáwọn òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì tó sì ti ń jẹ́ àǹfàní fún àwọn tó lé ní 27,000 lórí ètò ìlera."
Adeleke ṣàlàyé pé gbogbo ìlú àti agbègbè ní ìopínlẹ̀ Osun ni àwọn ti ń ṣe iṣẹ́ àkànṣe bíi ṣíṣe ọ̀nà, kíkọ́ ilé ẹ̀kọ́, ilé ìwòsàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
'Ọ̀pọ̀ ló rò pé mi ò ní le ṣe iṣẹ́ nígbà tí mo bá di gómìnà nítorí ijó tí mo máa ń jó'
Ó sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò gbàgbọ́ pé òun máa rí iṣẹ́ kankan ṣe nígbà tí òun ń dupò gómìnà nítorí bí òun ṣe máa ń jó ní gbogbo ìgbà t5í òun bá ti wà lóde àmọ́ tí òun pa gbogbo èrò bẹ́ẹ̀ mọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú pẹ̀lú àwọn nǹkan tí òun ti gbé ṣe lẹ́nu tí òun ti dé ipò.
Ó sọ pé àwọn nǹkan tó jẹ́ ìpèníjà fún òun nígbà tí òun di gómìnà ni gbèsè owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ tí ìjọba tí òun bá fi kalẹ̀ fún òun.
Ó fi kun pé inú òun dùn pé ìjọba òun ti rí bíi oṣù mẹ́sàn-án sí mẹ́wàá san nínú àwọn gbèsè náà.
Gómìnà náà tẹ̀síwájú pé àwọn àkànṣe iṣẹ́ tí Rauf Aregbesola ń ṣe lọ nígbà tó wà lórí ipò àmọ́ tí Gboyega Oyetola pa tì jẹ́ nǹkan tí kò tẹ́ òun lọ́rùn nígbà tí òun gba ipò, tí òun sì gbìyànjú láti parí wọn lẹ́nu ọdún méjì òun lórí ipò.
Bákan náà ló sọ pé òun kò ya owó kankan láti ìgbà tí òun ti gbàkóso ìpínlẹ̀ Osun nítorí òun ti pinnu pé òun kò fẹ́ fi kún gbèsè tó ti wà lọ́rùn ìpínlẹ̀ náà tẹ́lẹ̀.
Adeleke ní irọ́ ni ìròyìn táwọn ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ń gbé kiri pé àwọn ti sọ ìpínlẹ̀ náà sínú gbèsè nítorí àlékún ti bá iye tí àwọn ń gbà láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀, táwọn sì ń ṣe àmójútó iye tó ń wọlé náà láti ri pé ó ń tó àwọn lò.
Nítorí pé mi ò ní bàbá ìsàlẹ̀ ni owó tó ń wọlé fún ìpínlẹ̀ Osun ṣe ń tó ná
Gómìnà Ademola Adeleke sọ pé gbogbo ìgbà ni òun máa ń sọ ọ́ pé òun kò ní bàbá ìsàlẹ̀ kankan tó ṣe àtìlẹyìn fún ìyànsípò òun láti di gómìnà.
Ó ní èyí ṣe ìrànwọ́ fún ìṣèjọba òun nítorí kò sí ẹni tó ń retí pé òun máa fún òun níṣẹ́ tàbí máa san owó kan fún ní oṣooṣù.
Ó sọ pé ẹ̀gbọ́n òun, Deji Adeleke tó ṣe ìrànwọ́ owọ fún òun nígbà tí òun fẹ́ dupò náà kò fi ìgbà kan bèèrè owó lọ́wọ́ òun rí, tó sì máa ń bá òun sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìgbà láti má gbàgbé àwọn ìlérí tí òun ṣe fún àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Osun lásìkò ìpolongo ìbò náà.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn táwọn kan fi kàn-án pé àwọn ẹbí àtàwọn ọmọ ìlú rẹ̀ nìkan ló ń yàn sípò, ó ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ẹ̀sùn náà àti pé òun kò fi ẹ̀yà, ìlú tàbí ẹ̀sìn ṣe láti máa yan àwọhn èèyàn sípò.















