A ti ń bá Egypt jíròrò lórí bí a ṣe máa fi ọkọ̀ kó àwọn ọmọ Nàìjíríà kúrò ní Sudan - ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìjọba Nàìjíríà ní àwọn ti ń sa gbogbo ipá àwọn láti ri dájú pé àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní orílẹ̀ èdè Sudan ni àwọn dá padà sílé.
Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè, Geoffrey Onyeama tó sọ àrídájú yìí ní àwọn ti ń ṣiṣẹ́ láti ri pé àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní orílẹ̀ èdè náà padà sílé láyọ̀ àti àláfíà.
Onyeama ní ohun tó ń dá àwọn dúró láti kó àwọn ènìyàn náà ni pé kò sí ààyè láti lo ọkọ̀ òfurufú ní Sudan báyìí nítorí wàhálà tó ń ló lọ́wọ́ ní orílẹ̀ èdè náà.
Ó ní ọkọ̀ ni àwọn fi lè kó àwọn ènìyàn ọ̀hún tí àwọn sì nílò àṣẹ ìjọba Sudan láti kó wọn gba Egypt lábẹ́ ààbò tó péye.
Mínísítà náà ní tí ó bá máa fi tó ọjọ́ méjì sí mẹ́ta àwọn máa ti fẹnukò pẹ̀lú ìjọba Sudan àti ti Egypt tí àwọn yóò si ti mọ bí àwọn yóò ṣe kó àwọn ènìyàn náà kúrò.
Bákan náà ló sọ àfọ̀mọ́ rẹ̀ wí pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni pé ìjọba Nàìjíríà kò kóbi ara sí ìṣòro tí àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní orílẹ̀ èdè náà ń kojú.
“Kò sí ẹni tó mọ̀ wí pé wàhálà tó ń wáyé ní Sudan máa fẹjú tó báyìí, ààbò ẹ̀mí àti dúkìá gbogbo ọmọ Nàìjíríà nílé lóko jẹ́ èyí tó jẹ ìjọba lógún.”
Ó fi kun pé ẹgbẹ̀rún márùn-ún àbọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ti fi ìfẹ́ hàn sí pé àwọn ti ṣetán láti padà wá sílé tó sì ní púpọ̀ nín;u wọn lọ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́.
Onyeama tún tẹ̀síwájú pé àwọn àjọ ìjọba tún ti ń gbìyànjú láti pèsè ohun ìdẹ̀kùn fún àwọn ènìyàn náà.
Ẹ̀yin ọmọ Naijiria ni Sudan, ẹ ṣì dúró sọ́hun o! Ìdí tá ò fi lè kóo yín wálé lásìkò yìí rèé

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ṣaaju ni alaga ajọ to n ri si ọrọ awọn Naijiria to wa loke okun, Honorebu Abike Dabiri-Erewa ti fesi lori ọrọ awọn akekọọ ọmọ Naijiria to wa ni orileede Sudan ti wọn ti n pariwo pe ki ijoba Naijiria wa gba awọn.
Abike Dabiri jẹ ko di mimọ pe ko ni ṣeeṣe ki awọn ko awọn ọmọ Naijiria to wa ni orileede Sudan wale bayii pẹlu bi ogun se n sele lọwọlọwọ to si n pa awọn araalu lara to fi mọ awọn ara ile okere to n gbe nibẹ.
Dabiri ni bo tilẹ jẹ pe awọn ti n se eto lati jẹ ki wiwa sile wọn wa si imuṣẹ, amọ kii ṣe lọwọlọwọ yii.
Ija to n waye ni Sudan ti gba ẹmi eeyan to to irinwo bayii to si ti jẹ ki ọpọlọpọ farapa lati igba to ti bẹrẹ ni ọjọ Abamẹta to kọja laarin awọn ikọ ogun orisi meji ti ọkan wa lẹyin ọgagun Fattah al-Burhan ati igbakeji rẹ, Mohammed Hamdan Daglo to n dari ikọ afarajologun ti wọn n pe ni Hemeti.















