Ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún ọlọ́pàá tó pa awakọ̀ èrò nítorí N100

Okunrin naa

Oríṣun àwòrán, Others

Ile ẹjọ giga nipinlẹ Rivers, ti da ẹjọ iku fun ọkùnrin ọlọpaa kan to pa awakọ bọọsi nitori ọgọrun Naira lọdun 2015.

Onidajọ Elsie Thompson sọ lasiko to dajọ pe awọn ẹri to wa niwaju ile ẹjọ fihan pe ọlọpaa naa to jẹ sajẹnti nigba kan, mọọmọ yinbọn mọ awakọ ọhun, David Legbara, to si pa a.

Adajọ ṣapejuwe ọlọpaa naa, James Imhalu, gẹgẹ bi ẹni ti inu rẹ ma ń dun lati yinbọn ni gbogbo igba.

O ni ko dara ti iru rẹ bá n gbe ni awujọ.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?

Ọdun 2015, ninu oṣu Kẹjọ, ni iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Wimpy ni Rumuepirikom ni ìjọba ibilẹ Obio Akpor.

Ni ọjọ naa, ikorita Wimpy, ní opopona Ikwerre, ni ọlọpaa naa, Sajẹnti James Imhalu yinbọn pa awakọ naa lasiko to da a duro nitori ọgọrun Naira owo rìbá.

Oloogbe Legbara, nikan ni ọmọkunrin kan ṣoṣo ti awọn obi rẹ bí, oun naa si lo n gbọ bukaata ẹbi rẹ.

Koda, iyawo rẹ loyun oṣu mẹjọ sinu nigba ti o ku.

Iku rẹ fa iwọde nla laarin awọn awakọ eero ati awọn kọ̀ndọ́kítọ̀ fun ọpọlọpọ ọjọ, eyi to fa ọ̀wọ́n gogo ọkọ ati sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ paapaa lati agbegbe Mile 3 si Rumuokoro.

Koda, àwọn awakọ naa fẹ ẹ ṣe iwọde yika ilu Port Harcourt ni ihoho, nitori bi awọn ọlọpaa ṣe n yin afẹfẹ tajú tajú si wọn, ko to o di pe Gomina Nyesom Wike bẹ wọn pe ki wọn o ṣe suuru.