Ó ń rúgbó bọ̀! Ẹ wo ohun tí ẹgbẹ́ ASUU dá lárà níbi ìwọ̀dé Fásitì Ibadan àti ohun tí wọ́n sọ fún ìjọba

Oríṣun àwòrán, BBCYORUBA
Awọn ọmọ ẹgbẹ olukọ Faṣiti (ASUU), ti ile iwe giga ilu Ibadan (UI), ile ẹkọ Fasiti Ladoke Akintola (LAUTECH) ati Fasiti ti Ilorin ti fi ẹhonu han si ohun ti wọn ṣapejuwe gẹgẹ bi ijiya awọn ọmọ ẹgbẹ ASUU lati owo ijọba apapọ ati awọn aṣoju rẹ.
A le ranti pe ASUU bẹrẹ iyanṣẹlodi ni ọjọ kẹrinla Oṣu keji ọdun yii lati jẹ ki Ijọba ṣe amuṣẹ awọn ileri ati adehun ti wọn fọwọ si pẹlu ẹgbẹ olukọ Faṣiti ni Oṣu kejila ọdun 2020.
Nigba ti o n ba awọn oniroyin sọrọ lakoko ifẹhonuhan, Alaga, ASUU ti Faṣiti Ibadan, Ayoola Akinwole ṣalaye pe ijọba apapọ ko ṣetan lati bọwọ fun iwe adehun ti o tọwọ bọ.
Wọn ni ijọba si fi oju tẹnbẹlu ẹgbẹ oṣiṣẹ nipa sisan idaji ọwọ oṣu fun awọn ọmọ ẹgbẹ ASUU losu to kọja.

Oríṣun àwòrán, BBCYORUBA
Ayoola ni gẹgẹ bi ẹgbẹ awọn ọjọgbọn, o jẹ ojuṣe ẹgbẹ olukọ faṣiti (ASUU) lati daabo bo awọn ile-ẹkọ giga ati lati ja fun anfani awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ati awọn akẹẹko ile-iwe giga kaakiri orilẹede Naijiria.
Remi Adeyemo, aṣoju awọn obi awọn ọmọ to wa ni faṣiti ijọba bẹ ijọba apapọ lati fi ọwọ ti o tọ wẹ awọn ile iwe giga kaakiri orilẹede yii.
Remi ni ijọba gbọdọ ṣetan lati na owo si awọn ile iwe giga faṣiti nitori ẹkọ jẹ ẹtọ fun gbogbo awọn ọdọ orilẹede yii. Adewole Adeyinka aarẹ akẹẹko ile-iwe giga faṣiti ilu Ibadan sọ wi pe awọn akẹẹko ṣetan lati pẹlu awọn olukọ fasiti ile iwe giga yan iṣelodi nitori ọpọlọpọ awọn eroja ti wọn fi n kọ awọn ni ile iwe nisisiyii kii ṣe ti igbalode.
Adeyinka ni ẹtọ awọn akẹẹko ni awọn olukọ awọn ja fun.
O rọ ijọba apapọ lati yọnda owo oṣu awọn olukọ faṣiti ati lati bu ọwọ fun adehun to wa laarin ẹgbẹ olukọ faṣiti ASUU ati ijọba apapọ.















