‘Àjẹkún ìyà yóò jẹ ẹ̀yin aráàlú báa bá ń fi àwọn aláílóye òṣèlú silẹ̀ kí wọ́n máà ṣeé ní Oyo’
"Èmi mọ gbogbo kọ̀rọ̀ àti ìgborò òṣèlù, kò yẹ ká máa gbà àwọn tí kò mọ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ láti dárí ìlú."
Oloye, amofin agbẹjoro, oniṣowo ni Sharafadeen Abiodun Alli to n dije du ipo Sẹnetọ ni ẹkun Guusu ipinlẹ Oyo.
O ni ẹmi ati sin ilu ni oun ni toun fi fẹ du ipo Sẹnetọ bo tilẹ jẹ pe oloye ilu ni to si tun jẹ Amofin ati Oniṣowo.

O ni ofin ni wọn n lọ ṣe nile igbimọ aṣofin kii ṣe bi awọn kan ṣe n ṣee.
Bakan naa lo ni gbogbo nnkan ti ko kan ijọba apapọ ti wọn n da si.
“Táa bá fi wèrè sílẹ̀ kó ṣe òkú ìyà rẹ̀ bó ṣe wù ú, yóò ṣe é yánmọ-yànmọ ni”. O mẹnu ba awọn nnkan ti yoo yipada to ba de ipo ati awọn nnkan ti yoo ṣe fun araalu.












