Òtútù àmújù àti ìjí líle kọlu Amẹrika, èèyàn méjìlá kú, 1.5m èèyàn kò rí ìna ìjọba lò

US winter storm

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O kere tan, eeyan mejila lo ti jade laye bayii nilẹ Amẹrika lẹyin ti atutu amuju ati iji lile kọlu orilẹ-ede naa.

O kere tan, miliọnu kan abọ eeyan ni ko ri ina ijọba lo mọ, wọ si ti wọgile ọpọ irinajo ọkọ ofurufu nitori bi oju ọjọ ṣe ri.

Iji naa ni wọn ni o fẹ fun nnnkan bii ẹgbẹrun meji maili lati ilu Texas, l’Amẹrika titi de Quebec, ni Canada.

Bẹẹ naa ni iji naa ṣakoba fun oju ọjọ lagbagbe Great Lakes, to jẹ ala ilẹ to so orilẹ-ede Amẹrika ati Canada papọ.

Ni Canada, ẹgbẹlẹgbẹ eeyan ni ko ri ina ijọba lo lagbegbe Ontario ati Quebec nitori iji lilẹ ọhun.

Awọn agbegbe mii bii British Columbia titi de Newfoundland n fara kasa ojutu amuju bayii.

Ileeṣẹ to n ri si ọrọ oju ọjọ l’Amẹrika, National Weather Service (NWS) sọ pe otutu ọdun yii lagbara ju ti atẹyinwa lọ.

Lagbegbe South Dakota, niṣe lawọn eeyan n jo aṣọ ti wọn fi n ya ina nitori otutu naa ti pọ ju fun wọn.

Lara awọn agbegbe mii ti ẹkun omi ti n gba ala wọn bayii ni New England, New York ati New Jersey.

Wọn ti kede fun awọn eeyan ipinlẹ Louisiana, Alabama, Florida ati Georgia pe ki wọn maa reti otutu to lagbara.

Yatọ si otutu ati iji lile, oju ọjọ naa tun ti fa awọn awọn ijamba ọkọ, nibi ti nnkan bii aadọta ọkọ ti kọlu ara wọn lera-lera, ti awakọ meji si lọ si.

Wayi o, wọn ti wọgile nnkan bii 5,600 irinnajo ọkọ ofurufu to yẹ ko waye lọjọ Ẹti kaakiri orilẹ-ede naa.