Olufemi Ajadi Oguntoyinbo: Oṣù méjì tí mo bá dé ìjọba ni àwọn ará ìpínlẹ̀ Ogun a ti rí àyípadà rere tó pọ̀

Àkọlé fídíò, Olufemi Ajadi Oguntoyinbo: Oṣù méjì tí mo bá dé ìjọba ni àwọn ará ìpínlẹ̀ Ogun a ti rí àyí

Mo fẹ ṣe ayipada si igbe aye awọn eeyan mi ni mo ṣe jade dije dupo gomina Ogun- Ajadi Olufemi

Asoju Olufemi Ajadi Oguntoyinbo ṣalaye fun BBC pe nitootọ ni oun ko ni iriri ninu iṣelu to pọ tẹlẹ ṣugbọn oun ṣetan lati mu inu awọn eeyan ipinle Ogun dun.

Oun lo jade dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Naijiria tuntun ti wọn pe ni New Naigeria People's Party.

O sọ bi ohun to ṣẹlẹ ni 1993 lẹyin wahala June 12 Moshood Kashimaawo Olawale Abiola da rogbodiyan sile nigba naa ni ninu ipinnu oun.

Nakan naa ni Ajadi sọrọ nipa ijakule ti awọn egbẹ oṣelu ti ko ba awọn ara ilu atyi ohun to pinnu lati ṣe fun awọn eniyan ipinlẹ Ogun laarin oṣu meji ti oun ba gba ijọba.