Ọ̀pọ̀ èèyàn tó lárùn arunmọléegun ni kò lówó láti gba ìtọ́jú rẹ̀

- Author, Makuochi Okafor
- Role, BBC News
- Reporting from, Lagos
Maureen Nwachi, ẹni ọdun mọkandinlogoji lati ilu Eko ni irora arun arunmọleegun.
O ṣe apejuwe irora naa bi igba ti ilẹkun ọkọ ba mu eeyan lọwọ, tabi ki wọn maa fi haamọ gba nkan.
Maureen ni arun arunmọleegun, eyi ti o jẹ arun inu ẹjẹ to n ba ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eeyan finra lagbaaye ni púpọ ninu wọn wa ilẹ Africa ati orilẹede India.
Arun yii maa n ṣakoba eroja aṣaraloore inu ẹjẹ to maa n gbe afẹfẹ kaakiri ara eeyan.
Arun arunmọleegun maa n ṣe ayipada sẹẹli ẹjẹ pupa ninu ara ni.
Eyi ṣi maa n pa awọn sẹẹli ninu ara, leyi to maa n fa irora fawọn eeyan to ba ni arun naa.
Ẹwẹ, arun beta-thalassemia kii jẹ ki ara maa pese afẹfẹ ninu ẹjẹ.
Lai si afẹfẹ inu ẹjẹ yii ti wọn n pe ni haemoglobin, afẹfẹ ko le de gbogbo ara.
To fi di akoko yii, itọju meji lo wa fáwọn to ba ni arun yii - fifa ẹjẹ si wọn lara ati lilo oogun ti wọn n pe ni hydroxyurea.
Ọna abayọ gboogi si arun yii ni nipa ṣiṣe ipaarọ mundunmundun inu eegun lati ara elomiran.

Irinṣẹ itọju arun arunmọleegun ni wọn n pe ni 'Genetic scissors'
Orilẹ-ede UK ni orilẹede akọkọ lagbaaye lọdun 2023 ti yoo fi ontẹ lu irinṣẹ itọju arun arunmọleegun ti wọn n pe orukọ rẹ ni Crispr.
Ni oṣu Kejila ọdun 2023, orilẹede America naa ṣe ifilọlẹ meji irufẹ itọju yii.
Irinṣẹ yii ti wọn maa n pe nigba mii ni "genetic scissors" maa n ṣe afihan DNA alaisan arunmọleegun ti o si maa n gbogun ti awọn gin-in-ni ti ko dara.
Awọn dokita ko le sọ igba ti itọju yii le pẹ to, amọ, lọwọ yii ireti to dara ni o ni.
Mejidinlọgbọn ninu eeyan mọkandinlọgbọn to kopa ninu ayẹwo itọju yii ni ko mọ irora fun ọdun kan lẹyin ti wọn gba itọju tan.
Bakanna, mọkandinlogoji ninu eeyan mejilelogoji to larun beta-thalassemia ni ko gba ẹjẹ fun ọdun kan lẹyin ti wọn gba itọju yii.
Amọ, lọwọ yii, itọju arun arunmọleegun ti wọ-ọn pupọ.
Oriṣii itọju meji ti orilẹ-ede America ṣawari rẹ yoo na alaisan kan ni owo to le ni miliọnu meji si miliọnu mẹta dọla.
Itọju naa lagbara gan an eyi ti ẹni to ba ni arun yii yoo lọ gba nile iwosan nla.
Bo tilẹ jẹ pe nnkan idunnu ni bi awọn oluwadii ti ṣe awari itọju arun yii, ọpọ awọn to ni arun yii ni ko ri owo lati gba itọju rẹ nibi yi aisan naa ti n ṣọṣẹ julọ.

Ida 80% awọn to larun arunmọleegun lagbaaye lo wa ni ilẹ olooru Africa
Eeyan to le ni miliọnu marun un to larun arunmọleegun lo wa ni ẹkun olooru ilẹ Africa, gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe sọ lọdun 2021.
O kere tan egberun kan ọmọ ti wọ́n n bi ni Africa lo n larun arunmọleegun lojoojumọ.
Orilẹede Naijiria ni arun arunmọleegun ti pọ julọ lagbaaye, o pọ ni DR Congo naa.
Eyi lo mu ki awọn ṣọọṣi kan maa kan nipa fawọn to ba fẹ ṣe igbeyawo lati ṣe ayẹwo ẹjẹ wọn ki wọn le mọ bo ya wọn o ni bi ọmọ to maa larun arunmọleegun.
Oogun wa t'awọn ọmọ Naijiria le gba to fi mọ ẹjẹ, amọ, ọpọ eeyan ni ko lowo lati gba itọju yii.
Eyi lo n jẹ ki ọpọ wa ninu irora ti ko ṣe fi ẹnu sọ.
Bakan naa ni ọmọ ṣori kaakiri awọn orilẹede Africa mi, tori ijoba ṣi n wa ojutuu si awọn arun mi bii HIV/AIDS, igbẹ-gbuuru, iba ati ikọ-feere.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dokita Stella Rwezaula, to n ṣiṣẹ nile iwosan ijọba Muhimbili niluu Dar-es-Salaam lorilẹede Tanzania sọ pe ọpọ eeyan to larun arunmọleegun ko lowo lati ṣe itọju rẹ.
O ni o yẹ ki ìjọba ṣe iranwọ fun iru awọn eeyan yii lati le maa gba itọju ti wọn nilo.
Dokita Ogunkoya naa kin akẹgbẹ rẹ lẹyin.
O ni o yẹ ki itọju arun arunmọleegun wa ninu eto ilera ti ijọba n ṣe fun araalu.
Bakan naa ni o sọ pe o yẹ ki ijọba ṣe ẹdinwo oogun t'awọn eeyan to larun yii maa n lo fun itọju wọn.
Dokita Ogunkoya fẹ ki awọn ile iwosan maa ṣe ayẹwo fawọn ọmọ ikoko ti ko tii ju oṣu mẹta lọ, ki wọn le tete máa bẹrẹ itọju fawọn to ba ni arun arunmọleegun ninu wọn.
Amọ, Dokita Akshat Jain ni yoo pẹ ki itọju arunmọleegun pẹlu imọ ijinlẹ igbalode to de ọdọ awọn to larun yii nilẹ Africa.

Oríṣun àwòrán, Dr Akshat Jain
'O dabi ala ni fawọn eeyan India to larun arunmọleegun'
Nigba ti arun arunmọleegun wọpọ ni Naijiria, eyi to da bíi rẹ to jẹ arun ajogunba inu ẹjẹ mii, beta-thalassaemia lo wọpọ ni India.
Gẹgẹ bi ilẹ Africa, ọpọ to larun yii ko lowo lati ṣe itọju ara wọn.
Ọpọ ọmọbibi orilẹede India lo n san idaji owo ti wọn fi n tọju ara wọn.
Anubha Taneja to fi ilu Delhi ṣe ibugbe jẹ ọkan lara awọn to n bẹbẹ iranwọ fawọn to larun yii.
O ni niwọn igba ti o dun leti lati gbọ pe awọn onimọ sayẹnsi ti ṣawari itọju arun naa l'ọna to rọrun, Taneja ni ati maa ri ẹjẹ fa sawon eeyan lara ṣi nira di akoko yii.
Taneja ni o yẹ ki ijọba wa ọna lati ri pe awọn eeyan India ni anfani lati maa gba itọju igbalode arun thalassemia, pẹlu bi arun ọhun ṣe pọ julọ ni India.
O ni fun awọn to larun naa ni India lọwọ yii, o kan dabi ala ni.
Abẹrẹ kan ṣoṣo?
Koda, lorilẹede America gan an, ko to ọna mejila ti wọn ti n ṣe itọju igbalode fawọn to larun arunmọleegun, tori bi wọn ṣe nilo lati mojuto wọn lẹyin itọju ti wọn ba ti gba.
Amọ, ajọ Bill & Melinda Gates ti bẹrẹ iṣẹ lori wiwa oogun itọju arun arunmọleegun lọna to rọrun.
Dokita Mike McCune to n ṣiṣẹ pẹlu ajọ ọhun sọ fun BBC pe ajọ naa n ṣiṣẹ takuntakun lati wa oogun ti yoo maa ṣe itọju arun arunmọleegun lọna ti o rọrun.
O fikun ọrọ rẹ pe o yẹ ki oogun naa le jade ki a to ri ọdun marun un si asiko yii.
O ni "ero wa ni lati ṣawari oogun ti yoo maa ṣe itọju arun arunmọleegun ati HIV/AIDS ti yoo si jẹ abẹrẹ kan ṣoṣo."
Ajọ Bill & Melinda Gates n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ileeṣẹ bii Novartis to ti ni afojusun ni Naijiria tẹlẹ lori ọna lati jẹ k'awọn ti ko ri ọwọ họri le lanfaani si itọju arun arunmọleegun lọna igbalode.
O ni "a n foju sọna fun itọju arun arunmọleegun ti ko ni ju abẹrẹ kan ṣoṣo lọ- bo tilẹ jẹ pe eyi ko tii maa ṣẹlẹ bayii, a ni igbagbọ pe ko ni pẹ mọ ti yoo fi ṣẹlẹ."
Fun awọn eeyan bii Nwachi ni Naijiria, ko si ireti pe wọn le ma ri iranwọ lori arun ajogunba inu ẹjẹ yii laipẹ.















