Ìdí rèé tí Aston Villa fí jáwé lọ gbélé ẹ fún Steven Gerrard

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
Ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Aston Villa ti fi ọwọ osi juwe ile fun akọnimọọgba wọn Steven Gerrard lẹyin ti ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Fulham bu ewuro si wọn loju lana ninu ifẹsẹwọnṣe iligi ilẹ gẹẹsi.
Ikọ Aston Villa ti jawe olubori ifẹsẹwọnsẹ meji ninu saa yii, ti wọn si ti fẹ bọ ipele awọn ti yoo ja bọ sinu iligi keji.
Agbẹnusọ ikọ agbabọọlu Aston Villa ni “A fẹ dupẹ lọwọ Steven fun isẹ takuntakun and ifọwọsowọpọ rẹ pelẹ ikọ. A ki dada, ti gbadura pe ki ọjọla rẹ da.”
Gerrard lo gba isẹ lọwọ Dean Smith gẹgẹ bi akọnimọọgba ninu osu kejila lọdun 2021 lẹyin to kuro ni ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Rangers
Kí ló fà tí wọ̀n fí gbé ìgbésẹ náà?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Steven Gerrard, ẹni ọdun mejidinlogoji tiraka lati bori ifẹsẹwọnsẹ mẹtala ninu ogoji laarin oṣu mọkanla to fi jẹ akọnimọọgba ikọ agbabọọlu Aston Villa.
Igbesẹ naa waye lẹyin ti ikọ agbabọọlu Fulham din dundu iya fun wọn ni awọn alasẹ pinnu lati le Gerrard lọ.
Steven Gerrard ni aise dede awọn lo fa bi awọn sese kudiẹkudiẹ
“Aise dede lo koba wa ti a fi ba arawa nipa ti a wa loni. Bi mo ṣe ba ikọ naa nigba ti mo gba isẹ naa niyi. A gbinyanju lati ra awọn agbabọọlu tuntun lati mu wa kuro ninu lasigbo sugbọn a ko ri ẹnikẹni ra.”
“Jagunjagun ni mi , ninu ẹjẹ mi lowa ti ma si ma ja lọ titi ma fi ri nkan miiran sọ fun mi.
Lẹyin wakati kan to sọ eleyi ni isẹ bọ lọwọ rẹ gẹgẹ bi akọnimọọgba Aston Villa.















