Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa aṣojú-ṣòfin nílùú Abuja tó kú lẹ́ni ọdún 39

Oríṣun àwòrán, Ekene Adams/X
Iku o dọjọ, arun o doṣu, laarọ ọjọ Iṣẹgun ọjọkẹrindinlogun oṣu Keje yii ni iroyin sọ pe, Ekene Abubakar Adams, to jẹ ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja ti jade laye lẹni ọdun mọkandinlogoji.
Adams lo n ṣoju ẹkun idibo Chikun/Kajuru ipinlẹ Kaduna nile aṣoju-ṣofin niluu Abuja ki ọlọjọ to de.
Agbẹnusọ ile igbimọ aṣoju-sọfin l’Abuja, Akin Rotimi lo kede iku Adams ninu atẹjade kan to fi sita.
Iroyin kan sọ pe aṣofin Adams ku lẹyin to ti ṣe aisan fun igba pipẹ.
Aṣofin Adams ni alaga igbimọ ile aṣoju-ṣofin to n ri si ọrọ ere idaraya nile.
Aarẹ Tinibu, ile igbimọ aṣoju-ṣofin ṣedaro aṣofin Ekene Adams
Ile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja ti ṣapejuwe Adams gẹgẹ bi ọmọ ile to ni itara fun ere idaraya.
Bakan naa ni ile tun sọ pe ẹlẹyinju aanu ni Adams nigba aye rẹ.
Aarẹ Bola Tinubu naa ti kẹdun pẹlu ile igbimọ aṣofin agba l’Abuja ati ipinlẹ Kaduna lori iku aṣofin ọhun.
Aarẹ Tinubu tun kẹdun pẹlu ẹbi ati awọn ọrẹ oloogbe bakan naa.
Ninu ọrọ tiẹ, gomina ipinlẹ Kaduna, Uba Sani sọ pe Ekene jade laye lasiko ti ipinlẹ naa nilo rẹ julọ.
Amọ, gomina ni Adams fi apẹẹrẹ rere lelẹ ki o to jẹ Ọlọrun ni pe.
Ẹgbẹ oṣelu Labour Party to jẹ ẹgbẹ Adams ni iku rẹ ṣi n ṣe awọn ni kayeefi.
Julius Abure to jẹ alaga gbogbogbo ẹgbẹ naa ni Naijiria sọ pe inu oun bajẹ tori aṣofin to n sọ otitọ fawọn to wa ni ijọba lai naani ọjọ ori rẹ ti jade laye.
Ọgbẹni Abure sọ pe lootọ ni pe ọdun kan pere ni Adams lo nile aṣofin l’Abuja, ṣugbọn o sọ pe ipa nla ni o ti ni lẹkun Chiukun/Kajuru to ṣoju nipinlẹ Kaduna.
Alaga ẹgbẹ LP ṣalaye pe laipẹ yii ni Adams pin oriṣiiriṣii nnkan bii ọkọ, alupupu ati ẹrọ amunawa fawọn eeyan ni ẹkun rẹ.
Odu ni Ekene Adams lagbo ere bọọlu ni Naijiria ki i ṣe aimọ fun oloko
Ajọ NFF to n ri si ọrọ ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria naa ṣe idaro aṣofin to jẹ alaga igbimọ ile to n ri si ọrọ ere idaraya.
NFF ni Adams jẹ ẹnikan to ni in lọkan lati ri pe ere bọọlu dagba sii ni Naijiria ko to ku.
Ọdun 1985 ni wọn bi Adams to jẹ oniṣowo aladaani ati oloṣelu.
Koda, Adams tun ti figba kan ri jẹ agbabọọlu.
Odu ni Adams lagbo ere bọọlu ni Naijiria, ki i ṣe aimọ fun oloko.
Adams tun ti figba kan ri jẹ ogagba ikọ agbabọọlu Kada FC ati Remo Stars niluu Ikenne.
Adams ni aṣofin kẹta to ti ku bayii nile aṣoju-ṣoju niluu Abuja lọdun yii.
Ti ẹ o ba gbagbe, lọsẹ to kọja ni aṣofin Olaide Akinremi Jagaban to n ṣoju ẹkun ariwa Ibadan jade laye.
Ẹni ọdun mọkanlelaadọta ni Akinremi i ṣe ki ọlọjọ to de.
Ṣaaju loṣu Karun un ọdun 2024 yii naa ni aṣofin Isa Dogonyaro to n ṣoju ẹkun Babura/Garki nipinlẹ Jigawa ku lẹni ọdun mẹrindinlaadọta.















