Bí wọ́n ṣe ṣàwárí òkú ọmọ ipínlẹ̀ Anambra kan nílé ìtura Bauchi rèé

Oríṣun àwòrán, Chukwunonso Chukwujekwu
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bauchi ti kede pe awọn ti ri oku ọkunrin ọmọ ipinlẹ Anambra kan nile itura.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Ahmed Wakili ṣalaye fun BBC pe ẹyin ọjọ meji ti wọn ti n wa ọkunrin naa ni wọn to ṣawari oku rẹ nile itura ọhun.
Iroyin ni oloogbe naa wa nibi ajọyọ ọdun iṣu tuntun kan ṣaaju iku rẹ.
Wakili sọ pe “Iyawo ọkinrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Grace Chukwunonso lo lọ sọ ni agọ ọlọpaa ni ọgbọn ọjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2022 yii pe oun n wa ọkọ oun.”
“Obinrin naa sọ pe ọkọ oun kuro nile wọn, to si lọ si ṣọọbu wọn to wa ni Boi, amọ lati igba naa loun ti n wa.”
“Ni kete to fi ọrọ naa lọ ọlọpaa leti ni DPO agbegbe naa paṣẹ ki wọn maa wa ni kiakika ko to di pe wọn ri oku rẹ nile itura kan ni Tundun Wada, to wa lagbegbe Bogoro.”
“O wa nilẹ, itọ si n da lẹnu rẹ.”
Wakili sọ siwaju si pe nigba ti wọn yoo fi gbe de ile iwosan, ẹmi ti bọ lẹnu rẹ.
O pari ọrọ rẹ pe kọmiṣọna ọlọpaa ipilẹ naa ti paṣẹ ki iwadii bẹrẹ lori ohun to ṣokunfa iku rẹ.
Inu oṣu Kinni, ọdun 1985 ni wọn bi oloogbe ọhun, o si ti lo nkan bii ogun ọdun nipinlẹ Bauchi ṣaaju iku rẹ.












