Coronavirus: Adeboye ní àsìkò yìí lá mọ ẹni tó ń sin Ọlọ́run ní òtítọ́ àti òdodo

Oríṣun àwòrán, pastoreaadeboyeofficial
Olusọagutan fun ijọ Redeem, RCCG, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye ti fọwọ gbaya pe arun Coronavirus ko lee ran awọn ọmọ ijọ oun to ba sin Ọlọrun deede.
Olusọagutan Adeboye fọwọ idaniloju naa sọya ninu fidio kan to fi soju opo Instagram rẹ, pastoreaadeboyeofficial, eyi to fi n ba awọn ọmọ ijọ rẹ sọrọ lori idi ti wọn fi gbọdọ sun mọ Ọlọrun lasiko yii.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Alufa ijọ RCCG naa wa tọkasi ẹsẹ bibeli kan, Orin Dafidi ori kọkanlelaadọrun, ẹsẹ ikinni to ni, ẹni to n joko nibi ikọkọ ọga ogo, yoo maa gbe abẹ ojiji Olodumare, to si ni eyi ni yoo jẹ ipin awọn ọmọ ijọ oun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Taiwo Oredein rèé, àgbà òṣèlú tó parí ayé rẹ̀ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n
- Èdè àìyedè bẹ̀rẹ̀ lórí bí àgbélẹ̀rọ òyìnbó Nàíjíríà ṣe wọ ìwé atúmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì Oxford
- Ògbólógbòó ìjàpá rèé, tó bí ọmọ 800 kí ìran rẹ̀ má ba à parun
- Buhari o, tètè ṣètò àtúntò Nàíjíríà ká le è dènà ogun abẹ́lé lẹ́ẹ̀kejì - Obasanjo figbe bọnu
- Nàíjíríà, ẹ wo bí àwọn ìlú ńlá-ńlá ṣe ń dènà ìtànkálẹ̀ Coronavirus, ẹ fi ṣe àwòkọ́ṣe
- Onínúfùfù ni Saheed Oṣupa, ṣùgbọ́n èèyàn dáradára ni-Taye Currency
Adeboye, ẹni to rọ awọn ọmọ ijọ naa pe, ki wọn sin Ọlọrun ju ti tẹlẹ lọ, ki wọn maa jere ọkan, ki wọn si maa da ijọ silẹ si , wa salaye pe, asiko yii ni Ọlọrun yoo se iyatọ laarin awọn to n sin-in lotitọ ati lododo, yatọ si awọn ti ko sin.

Oríṣun àwòrán, pastoreaadeboyeofficial
Bakan naa lo sọ fun wọn pe gbogbo adura wọn lasiko yii ti ijọ naa wa ninu aawọ ati adura, ni Ọlọrun yoo gba, ti yoo si fun wọn ni ẹri to pọ, yoo maa gbe wọn ga latinu ogo bọ sinu ogo nitori oun ti ke pe Ọlọrun nitori wọn.
"Mo fẹ fi da yin loju pe ko si kokoro arun kankan ti yoo sun mọ sakani yin. Mo gbagbọ pe asiko yii ni Ọlọrun yoo fihan wa gbangba pe iyatọ wa laarin awọn to ba n sin-in tọkantọkan ati awọn to kẹyin si."








