Coronavirus: Ìwàdìí ní omi ara ẹni tó bá ní àrùn náà leè ta sára ọ́pọ́ èèyàn níbí tí èrò bá pọ̀ sí

Ọkunrin to n fọn oogun apakokoro

Oríṣun àwòrán, Reuters

Saaju la ti sọ fun yin pe kaakiri agbaye ni aarun Coronavirus ti wa bayii, awọn alarun naa si ti pọ lawọn orilẹede miran ju ti orilede China to ti bẹrẹ si ni ja rain lọ, yatọ si Antartica ti ko ti i de.

Bẹẹ si ni ọna lati gbogun ti aarun Coronavirus ni awọn ilu nlanla ati lawọn orilẹede ti awọn eniyan ti n fi ẹgbẹkẹgbẹ lee jẹ ipenija.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Diẹ si ree lara awọn ipenija to n waye lawọn ilu nlanla ati awọn ọna abayọ ti wọn fi n koju wọn.

coronavirus

Oríṣun àwòrán, AFP

Ọkọ Igboro:

Nitori pe aarun Coronavirus maa n tan kalẹ, ti omi ara ẹni to ba ni i, ba si ta si ẹlomiran lara, wahala lee de.

Eleyii si wọpọ ninu ọkọ igboro nitori awọn eniyan maa n joko ti ara wọn ni. Idi si ree tijọba ilẹ South Africa, italy ati South Korea se paṣẹ pe ki wọn fọ inu awọn ọkọ igboro, lọna lati dena itankalẹ arun naa.

Awọn ero to n wo idije ere bọọlu

Oríṣun àwòrán, AFP

Ibi ti ero pọ si:

Awọn ayẹyẹ to pe fun ipejọpọ ero bii idije ere bọọlu, jẹ ọkan lara ibi ti arun Coronavirus n gba tankalẹ.

Nitorinaa ni China ṣe fofin de idije Formula One Grand Prix ni ilou Shangai, ti wọn si sun idije naa siwaju.

Ni ilẹ Yuroopu bakan naa, idije formular one ati rugby pẹlu bọọlu afẹsẹgba ni wọn ti wogile fun saa yii na.

Bakan naa ni awọn ẹlẹsin kọọkan ti gbegile awọn ẹsin ti yoo mu ki ọpọ ero pọ si ibi kan, ni akoko naa.

Ile iwe:

Awọn olukọ ati akẹkọ

Oríṣun àwòrán, AFP

Ọpọlọpọ awọn ile iwe ni wọn ti pa ni awọn orilẹede ti arun Coronavirus ti de, lọna ati kapa itankalẹ rẹ.

Ni awọn ilu bii Japan, Thailand, Iran ati Iraq, awọn ile iwe alakọbẹrẹ ati girama pẹlu fasiti ni wọn ti gbe ilẹkun wọn tipa bayii.

Ilẹ Gẹẹsi ati Amerika ko paṣẹ ki wọn ti ileewe, amọ ile iwe mẹrin lo ti tilẹkun kilaasi lati le fọ agbeegbe naa mọ toni toni, lẹyin ti awọn ọmọ ileewe naa de lati orilẹede Italy.

Bẹẹ ni awọn obi ati alagbatọ ni wọn ti parọwa si pe ki wọn jẹ ki awọn ọmọ wọn joko si ile, ti wọn ba ti rinrin ajo lọ si awọn orilẹede bii Iran, China, Hong Kong, South Korea, Asia ati Italy.

Ibudo ayẹwo ilera kan

Oríṣun àwòrán, AFP

Ile iwosan:

Nitori ko tii si oogun oyinbo to lee koju arun yii nilẹ bayii, awọn ileewosan gbọdọ ṣetan lati gba awọn eniyan la ni kiakaia. Bakan naa lo yẹ ka yan awọn eniyan miran lati kọ awọn osisẹ eleto ilera wa lori ọna ti wọn yoo ti setoju alaisan Coronavirus.

Awọn obinrin to n fi ọsẹ apakokoro fọ ọwọ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Igbenipamọ:

Awọn eleto ilera ti gboriyin fun awọn eniyan pe wọn ni ilanilọye nipa Coronavirus. Amọ wọn rọ ijọba lati pese awọn yara ibusun miran fun awọn arinrinajo to n bo. Nitori ti wọn ko ba se bẹẹ, o seese ki awọn eeyan ti wọn yasọtọ naa sa kuro lọ sita.