Leap Year: Jedidiah ní òun jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin, ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ọjọ́ ìbí òun yóò wáyé

Àkọlé fídíò, Leap Year: Jedidiah ní òun jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin, ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ọjọ́ ìbí òun yóò wáyé

Ọjọ ibi se pataki, o se koko, idi si ree ti ọpọ eeyan fi maa n se ayẹyẹ rẹ ni ọdọọdun.

Amọ eyi ko ri bẹẹ fun awọn eeyan ti wọn bi ni ọjọ kọkandinlọgbọn osu keji ọdun, nitori wọn ko ni anfaani lati yayọ ọjọ ibi lọdọọdun.

Idi ni pe ọdun mẹrin-mẹrin lo maa n waye, eyi ta n pe ni Leap Year.

Koda, ọmọdekunrin kan ọmọ ọdun mẹrin, Jedidiah Adetunji salaye pe oun ti pe ọmọ ọdun mẹrin amọ ti oun ko tii fi oju kan ọjọ ibi oun ri loke eepẹ.