BBNaija 2019: Khafi ní òun àti Gedoni kò ní àjọṣepọ̀ rárá

Oríṣun àwòrán, @BBNaija
Ọlọ́pàá Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Khafi Kareem ti sọ wí pé òun kò tí ì bá ẹnìkẹ́ni ní àsepọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sí ìgbà yíí.
Khafi fi eyi lede lasiko ti wọn fun awọn ara ile Big Brother Naija laye lati sọ awọn nkan ti awọn eniyan ko mọ nipa wọn.
O ni ko si otitọ ninu iroyin to gba ẹrọ ayelujara kan wi pe oun ati Gedoni Ekpata ba ara wọn ni asepọ ninu ile Big brother Naija.
Khafi ni oun ko ba ẹnikeni ni asepọ lati le bori gbogbo awọn isoro to koju oun fun ọpọlọpọ ọdun.

Oríṣun àwòrán, @BBNaija
Ọrọ naa di mimọ nigba ti Ike Oyeama ati Dianne sọ wi pe, awọn fi rọba idaboobo si ẹgbẹ ibusun Khafi ati Gedoni, ni awọn se sọ wi pe wọn lo o.
Gedoni naa ti o ti kuro ni ile Big Brother Naija naa sọ wi pe, ko si ibalopọ to waye laaarin oun ati Gedoni, amọ oun fẹran Khafi lọpọlọpọ.
- Ikọ̀ ‘Àmọ̀tẹ́kùn’ dé, tí yóò dẹ́kun ààbò tó mẹ́hẹ nílẹ̀ Yorùbá - Akeredolu
- Owó tí mo bá gbà padà lọ́wọ́ àwọn alájẹbánu ní màá fi gbé ètò ẹ̀kọ́ díde ní Ọyọ - Makinde
- "Àsìkò yí ló yẹ kí Yorùbá fi ìmọ̀ ṣọ̀kan"
- Ya isó nínú bàálù, kí o rí ìjà òfin!
- N kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nínú ikú akẹ́kọ̀ọ́ Fuoye, mo kẹ́dùn pẹ̀lú ẹbí wọn - Aya Fayemi
Ọjọ Isinmi ni a mọ boya won yoo le Khafi kuro ni Big Brother Naija, nitori awọn ara ile ti fi orukọ rẹ silẹ gẹgẹ bi ẹni ti wọn yoo le kuro ninu ile.








