Àyájọ́ òṣìṣẹ́: NURTW gba ẹ̀jẹ̀ lára àwọn òsìsẹ

Awọn osisẹ ni papa isire agege
Àkọlé àwòrán, Awọn oṣisẹ naa ni gbogbo awọn ti wọn ṣe leṣe ni wọn ti gbe lọ sile ìwosan.

Ọ̀rọ̀ di bóòlọ-o-yà fún mi lónìí, ní ibi ayẹyẹ àyájọ́ àwọn òṣìṣẹ́ tó wáyé ní pápá ìṣeré Agége nilú Èkó nígbàtí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ọlọ́kọ̀-èrò NURTW kan bẹ̀rẹ̀ sí ní gún àwọn òṣìṣẹ́ kan lọ́bẹ.

Eléyìí fa ìdàrúdàpọ̀, nínú èyí tí àwọn òṣìṣẹ́ fi fọ́nká, tí olúkúlùkù sì sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀.

Àwọn tó bá akọ̀ròyìn BBC Yorùbá, Olu Alebiosu, sọ̀rọ̀ ní, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ọlọ́kọ̀-èrò ọ̀hún ṣà dédé kọlù àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tí wọ́n tò kalẹ̀, ní ìgbáradì fún ètò yan-bí-ológun níwájú gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Akinwunmi Ambode, láti kásẹ̀ ayẹyẹ náà nílẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nígbàtí aféfé wàhálà náà yóò fi rọlẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ni wọ́n ti farapa.

Awọn osisẹ ni papa isire agege
Àkọlé àwòrán, Nígbàtí aféfé wàhálà náà yóò fi rọlẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ni wọ́n ti farapa.

Ọ̀gbẹ́ni Gbénga Olugunna, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lawọn ileesẹ tó ń se rọ́bà lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tó fara káásá ìkọlù àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ọlọ́kọ̀-èrò ọ̀hún.

Ò ni àwọn n gbaradi fún ètò yiyan-bí-ologun won, ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ọlọ́kọ̀-èrò náà bá ṣíná ìyà fún àwọn.

Gbogbo awọ̀n obinrin ni wọn kọlu

" Awọn ọmọ ẹgbẹ wa ti wọn kọlu pọ. Awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero lo si kọlu wa."

Gbogbo wa n to lati yan niwaju gomina nigba ti wọn ṣa dede gba ẹburu lai fẹ to. Gbogbo awọ̀n eeyan wa, paapaa julọ awọn to jẹ̀ obinrin ni wọn kọlu."

Gómìnà Akinwunmi Ambọ́de

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Gómìnà Akinwunmi Ambọ́de gan wà níkàlẹ̀ nígbàtí wàhálà yìí ń wáyé

Awọn oṣisẹ naa ni, gbogbo awọn ti wọn ṣe leṣe ni wọn ti gbe lọ sileewosan.

Akitiyan lati kàn si awọn adari ẹgbẹ NURTW lo ja si pabo

Nibi ti ikọ BBC Yoruba ti n ya aworan bi rukerudo yii ti n ṣẹlẹ, awọn ọlọpa kan ti ẹka amuṣẹya ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko gbiyanju, lati ja ohun eelo iyaworan wa gba, ki awọn lọgalọ́ga wọn kan to da sii.

Akitiyan lati kàn si awọn adari ẹgbẹ ọlọkọ ero NURTW nipinlẹ Eko, lo ja si pabo lasiko ti a fi nko iroyin yii jọ.