Trump: Bí wọn se ń pa Kristiẹ́ni kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà

Aworan aarẹ Buhari ati Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ mejeeji yoo sọrọ nipa eto aabo, ọrọ ajẹ ati idokowo laarin orilẹede mejeeji

Àarẹ ilẹ̀ Amẹrika Donald Trump, ti sọ pé ìṣekúpa àwọn ọmọlẹ́yìn Krístì nílẹ̀ Nàíjírià gbódọ̀ dópin.

Àarẹ Trump sọ̀rọ̀ náà, nígbà tí ó ń gbàlejò akẹgbẹ́ẹ rẹ̀ láti Nàíjíríà, Àarẹ Muhammadu Buhari nílé ìjọba Amẹrika, White House.

Àarẹ ilẹ̀ Amẹrika wá bu ẹnu àtẹ́ lu dídáná sun ṣọ́ọ̀ṣì nílẹ̀ Nàíjírià, o sì rọ ìjọba àpapọ̀ l'áti ṣe ètò ààbò tó múnádóko fún àwọn àwùjọ tọ́rọ̀ kàn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìmọ̀ràn Trump yìí wáyé lẹ́yìn tẹgbẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Krístì nílẹ̀ Nàíjírià CAN, sọ pé kí àarẹ Buhari kọ̀wé fipò sílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ àwọn darandaran tó ń fẹ̀mí àwọn èèyàn ṣòfò.

Sùgbọ́n Àarẹ Trump sọ́ di mímọ̀ pé, ìjọba ilẹ̀ Amẹrika yóò ṣísẹ́ pẹ̀lú ìjọba Nàíjírià láti fòpin sí àkọlùkọgbà náà.

Ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀, Àarẹ Muhammadu Buhari sọ pé, wàhálà àwọn darandaran níí se pẹ̀lú làáṣìgbò tó ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ Libya lẹ̀yìn iku ààrẹ Muammar Ghaddafi.