Ọ̀rẹ́ mẹ́rin dáwọ́jọ na ọkùnrin kan pa nítorí fóònù, wọ́n dèrò àtìmọ́lé ní Adamawa

Oga olopaa ipinle Adamwa

Oríṣun àwòrán, @AdamawaNPF

Àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́rin tí wọ́n dáwọ́jọ na Adamu Ahmadu ẹni ọdún méjìdílógún títí ẹ̀mí fi bọ́ ní ara rẹ̀ ni wọ́n wọ́ lọ sílé ẹjọ́ Májísíréètì ìlú Yola, ìpínlẹ̀ Adamawa.

Bawo ni ọ̀rọ̀ yii se ṣẹlẹ̀? ni ibere ọ̀pọ̀ eniyan nigba ti iroyin naa jade.

Ní ọjọ́ kejìlélógún, oṣù kìíní, ọdún 2022 ni Hamidu Umar tó jẹ́ ọmọ Báálẹ̀ àná ní Damare ní ìjọba ìbílẹ̀ gúúsù Yola, fẹ̀sùn kan Ahmadu, tó jẹ́ ọdẹ ní ilé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ìpínlẹ̀ Adamawa pé ó jí fóònù òun.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ahmadu sọ fún Umar wí pé òun kò mú fóònù, Umar fi àáké kọ́rí pé kó bá òun mú fóònù òun ni.

Èyí ló mú kí Umar àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta mìíràn, Sholle Manas, Faisal àti Nahau fi wọ Ahmadu lọ sí ilé àkọ́kù kan níbi tí wọ́n ti fi pákó àti àfọ́kù búlọ̀kù fìyà jẹ Ahmadu.

Lílù tí wọ́n lu Ahmadu ṣe okùnfà tí ọwọ́ rẹ̀ fi kán tó sì tún ṣèṣe ní gbogbo ara.

Ní ọjọ́ kẹtàlá, oṣù kejì, ọdún 2022 ni Ahmadu dákẹ́ sí ilé ìwòsàn Federal Medical Centre tó ti ń gba ìtọ́jú.

Àkọlé fídíò, Láti sẹ́ńtúrì kẹrìnlá ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine

Báwo lọ́wọ́ ṣe tẹ̀ wọ́n?

Ìwé ìròyìn Punch fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Baálẹ̀ Damare, Sahabo Umar ló gba Ahmadu kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó n lùú tó sì gbe lọ sí ilé ìwòsàn.

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà

Bákan náà ló lọ fi ọ̀rọ̀ náà tó àjọ ọlọ́pàá Wuro létí.

Ẹ̀wẹ̀, wọ́n ní Umar padà rí fóònù tó ń wá ọ̀hún ní orí àga nílé rẹ̀ nígbà tó padà sílé.

Àkọlé fídíò, Dapo Abiodun ò sọ fún mi pé òun á dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì o, èmi nàá ò kẹ̀rẹ̀ nínú òṣèlú láti kékeré - Modele Sarafa-Yusuf

Níbo lọ̀rọ̀ dé dúró?

Umar, lọ́jọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù kejì, ọdún 2022 sọ fún ilé ẹjọ́ pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun ṣùgbọ́n ẹnìkèjì tí wọ́n jọ ń jẹ́jọ́, Manas gbà pé òun jẹ̀bi.

Manas sọ fún ilé ẹjọ́ pé òun bá Umar, Faisal àti Nahau níbi tí wọ́n ti ń na olóògbè náà tí Umar sì sọ fún òun kí òun náà darapọ̀ mọ́ wọn láti fi ìyà jẹ Ahmadu.

Faisal àti Nahau ní ìròyìn ní wọ́n tí sá lọ báyìí.

Onídàjọ́ Dimas Gwamu ti sún ìgbẹ́jọ́ náà síwájú,