Electricity Subsidy: Ìjọba àpapọ̀ gbọdọ̀ fòpin si owó ìrànwọ iná ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, AFP
Àjọ tó n rí sí ètò ìná mọ̀nàmọ́nà ní Nàìjíríà ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àti ọgọ́ta bílíọ̀nù náírà ni ìjọba àpapọ̀ ń ná fún owó ìrànwọ́ iná.
Ó ní, ó ti tó àsìkò báyìí kí ìjọba fi òpin si irú ǹkan báyìí.
Gẹ́gẹ́ bi àjọ náà ṣe sọ, owó tí wọ́n ná lórí iná yiìí yẹ ki ó lọ sí ẹ̀ka ètò ìdàgbàsókè míràn, bíi ìlera, ètò ẹ̀kọ́, kí àwọn to n lo iná sí maa san owó iná ti wọ́n bá lò.
Igbákejì alága àjọ NERC Sanusi Garba, tó tún jẹ́ kọmísọ́nà ninu àjọ náà àwọn ṣe ṣe àgbékalẹ̀ ètò tí yóò maa sàfihan ǹkan ti wọ́n bá lò.
Ó ní ètò náà bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kini oṣu kẹsan, ọdún yìí, kí ó to dí pé wọ́n dáa dúró lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rìnlà. ìdádúrò náà kò ṣẹyìn ìpàdé tí o wáyé láàrin ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ìjọba àpapọ̀.
Garba ni, ó ṣe pàtàkì kí àwọn ará ìlú máa san owó iná ti wọ́n bá lò kàkà kí ìjọba sanwó ìránwọ́ lọ́dọọdún.
Ó ní ó ti tó ẹ̀ẹ̀mejì tí wọ́n ti ń lọbọ̀ lórí ọ̀rọ̀ owó iná náà nítori ọ̀rọ̀ àjàkalẹ́ ààrùn Coronavirus tó ń da gbogbo ilú láàmú.
Garba ni ó ti pọdandan láti ṣe àtúnto náà ńitori kò le wà bẹ́ẹ̀ títí láí, owó ni gbogbo àwọn ilé iṣẹ tọ́rọ̀ kan TCN láti pín iná sí ojúlé dé ojúlé.
Ó ní ìjọba ló tí ń sanwó ìrànwọ́ fún iná ti ará ilú bá ti lo láti ìgbà yìí wá.
" Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àti ọgọ́ta bílíọ̀nù náírà ní ìjọba san lópin ọdún 2019 fún owó ìrànwọ́n iná, èyí kìí ṣe ǹkan to le lọ títí láí".
Garba ni àjọ náà yóò máa ṣàmújútó bí ọ̀rọ̀ iná mọ̀nàmọ́ná yóò ṣe rọrùn fún àwọn olókoowòò ní Naijiríà, ó sì rọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti mọ ìdí tí ó fi yẹ kí ìjọba yọ owó ìrànwọ́ lórí iná mọ̀nàmọ́ná.













