Brexit: Ibò mọ́kàndínlógun péré ni Theresa May fi bọ́ lọ́wọ́ àwọn aṣòfin

Theresa May nigba nile ijọba lọjọ ru

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn ọmọ ile aṣofin Ilẹ Geẹsi dibo a ko ni igbékélé ninu rẹ mọ ni Ọjọru lati yọ adari ijọba Theresa May nipo, ṣugbọn o jajaboọ pẹlu ibọ mọkandinlogun.

May ni ibo okoolelọọdurun ati marun (325) ti awọn to si yọ nipo si ni ibo ọọdurun ati mẹfa (306).

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àkọlé fídíò, 'O yé kí ìbáṣepọ̀ Nàìjíríà àti UK dán mọ́rán síi lẹ́yìn àbẹ̀wò May'

Igbesẹ̀ yii lo tẹ̀le ijakulẹ to ri nigba ti awọn ọmọ ile dibo lati maa ṣe atilẹyin fun adehun to ṣe pẹlu ajọ EU lori Brexit.

Aworan lati ibi idibo ti wọn fẹ fi yọ Theresa May nile Gẹẹsi ni Ọjọru

Ninu ọrọ rẹ lẹyin ibo naa, May ni oun yoo maa ṣiṣẹ lati ri pe oun mu gbogbo ireti wọn lori ibo itagbagba, ninu eyi ti wọn ti fi han wipe awọn fẹ fi EU sile, wa si imuṣẹ.

Bẹẹ ni o tun ke pe awọn olori ẹgbẹ oṣẹlu, lati ba oun ṣe ipade pọ ki wọn baa le fi ero inu wọn han nipa ọna to tọ nipa Brexit.