Boko Haram: Mo le mú ki ènìyàn 137 kẹyin sí Shekau

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹni ọmọ ọdún méjìlélọ́gbọ̀n kan to jẹ ọ̀ga nínú Boko Haram tẹ́lẹ̀ rí Rawana Goni, ti rọ ikọ̀ ọmọogun Nàìjíríà kí wọn gba òun láyè láti pe Shekau to jẹ́ ọgá pátápátá fún Boko Haram, kí òun àti àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ̀ tó tó métàdílógóje lee jọ̀wọ́ ara wọn fún ìjọba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Goni tó wà lábẹ́ ìtóju ní ìgà àwọn ọmọogun orilẹ̀-èdè Nàìjíríà ní Maiduguri, sọrọ̀ yìí lásìkò tí ó ń bá akọròyìn NAN sọ̀rọ.
Ọmọ bíbí Bama ní ìpínlẹ̀ Borno ní Goni, ọga ní nínú ikọ̀ Boko Haram tẹ́lẹ̀ sùgbọ̀n tó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àwọn ọmọogun Nàìjíríà ní orílẹ̀-èdè Camroon, lẹ́yìn tó sá kúrò ní Sambisa l'ósu mẹ́jọ sẹ́yìn.
Ó ní òún ti di onírúurú ipò mú láwọn bùba Boko Haram ní Sambisa, Ó fi kún-un pe ipò tó òún dìmú kẹ́yìn ní ọ̀gá ààgbà apètù sááwọ̀, bákan náà ní òún tún máa so àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó ba yapa papọ̀.









