Èèmọ̀! Pósí ìyá tó kú ṣekú pa ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arakunrin kan ti kagbako iku ojiji lasiko to n ṣe eto isinku iya rẹ to doloogbe.
Samen Kondarura, ẹni ogoji dun, ni ajalu naa de ba lasiko to n gbe posi oku iya rẹ, Berta, ni igbe ẹyẹ ìkẹyìn.
Eto isinku naa waye ni Parinding Valley, ni ẹkun North Toraja, l'orilẹ-ede Indonesia.
Wọn ni lasiko ti awọn agbokujo n gbiyanju lati gbe posi naa si ori pepele kan ti wọn ti yasọtọ lati ṣe awọn eto ikẹyin si oku lara ni ibamu pẹlu aṣa agbegbe naa, ni ẹsẹ ọkan lara awọn agbokujo naa yẹ gẹrẹ lori akasọ, ti posi naa si jabọ lu Kondorura to n bẹ nisalẹ.
Loju ẹsẹ ti iṣẹlẹ naa waye ni wọn sare gbe Kandorura lọ si ileewosan nibi to ti papa gbẹmi mi.
Ileeṣẹ iroyin kan labẹle, Khaleej Times, sọ pe awọn alaṣẹ agbegbe naa to kuna lati gbe akasọ naa duro daada lo ni ẹbi iṣẹlẹ kaayefi ọhun.
Ṣugbọn, awọn ẹbi Kondorura pinnu lati maa ba awọn alaṣẹ naa ṣ'ẹjọ.
Nibayii, wọn ti sin oku Kandorura si ẹgbẹ iya rẹ.















