World Cup 2018: Òmì 1-1 ni Brazil ta pẹ̀lú Switzerland

Àwọn agbábọ́ọ̀lù Brazil àti Switzerland

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ikọ̀ Brazil kùnà láti jáwé olúborí nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ wọn nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé láti ọdún 1978

Agbaọjẹ ikọ agbabọọlu Brazil kuna lati jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ wọn ninu idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ lẹyin ti wọn ta omi 1-1 pẹlu ikọ Switzerland.

Eleyi nigba akọkọ ti orilẹede Brazil kuna lati jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ wọn ninu idije ife ẹyẹ agbaye lati ọdun 1978.

Philippe Coutinho lo kọ́kọ́ gba bọọlu sawọn fún Brazil, ṣugbọn Steven Zuber dayo naa pada fún ikọ̀ Switzerland.

Gbogbọ ìgbìyàjú Brazil lórí pápá pàbó ló jásí ti ifẹsẹwọnsẹ náà sì parí pẹ̀lú àmi ayò 1-1.

Nínú ifẹsẹwọnsẹ miran, Serbia fagba han Costa Rica pẹlu ami ayo kan s'odo.

Aleksandar Kolarov lo gba bọ́ọ̀lù wòmí-ń-gbáa sí ọ wolé ti Serbia ti jawe olubori.

Àwọn agbábọ́ọ̀lù Germany àti Switzerland

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ikọ̀ Germany ni ife ẹ̀yẹ àgbáyé wà lọ́wọ́ wọn lẹ́yìn tí wọ́n gbàá l'ọ́dún 2014 l'órílẹ̀èdè Brazil

Ìkọ agbábọ̀ọ̀lù Mexico náà fakọyọ nínú ìdíje rẹ̀ bí ó se fi ojú Germany gbolẹ̀ pẹlu ami ayo kan s'odo.

Hirving Lonzano lo gba ayo kan soso naa wọle ni iṣẹju marundinlogoji