Presidential Candidates: Ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ ni àbọ̀ EU lóri ìbò 2019

Olùdíje dupò ààrẹ to tó ọgọta nínú ìdìbò gbogboogbò ọdun 2019 ti bu ẹnu àtẹ lu ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party, PDP, àti olùdije lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ náà, Atiku Abubakar, lóri ọ̀rọ̀ awuyewuye to n waye nipa oju òpó ayélujára àjọ elétò ìdìbò, èyí ti wọ́n sàpèjúwe pé, ọ̀rọ̀ ti kò nílári ni.
Bákan náà ni wọ́n bu ẹnu atẹ́ lu àbájáde ìwádìí EU lóri bi ètò ìdìbò ṣe lọ ni Nàìjíríà, tí wọ́n si sàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bii èyí ti kò jágara tó, ti kò si tọ ìlànà òfin ìdìbò.
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ naa, lábẹ àbùrada ẹgbẹ gbogbo olúdije dupò ààrẹ to to ọgọ́ta niye àti àwọn alága ẹgbẹ́ wọ́n (Joint Forum of Sixty Presidential Candidates àn national Chairmen), sọ èyí di mímọ̀, lásiko ti wọ́n pé ìpàdé pẹ̀lú àwọn akọroyin.
Alhaji Muhammed Shittu lo soju fun ẹgbẹ naa, to si sàlàyé pé ajọ INEC kún ojú òsùwọ̀n tó.
Shittu ni "a ń tẹnu mọ pé, awuyewuye lori ọ̀rọ̀ oju opo ayelujara INEC kò ni ìtùmọ kankan, nítori pé, nínú gbogbo ìpàdé ti a se ki ètò ìdìbò tó dé, kò si ìgbà ti a jọ sọ̀rọ̀ lóri lílo oju opo ayélujára láti fí èsì ìdìbò ránṣẹ́, ọ̀nà láti yẹ̀yẹ́ àjọ elétò ìdìbò lásán ni."
Wọ́n fi kún pé " A rọ ààrẹ Muhammadu Buhari lati yara buwọlu àbádofin lóri àtunṣe to wáye nínú iwé òfin ilẹ wa, eyi to nii ṣe pèlu ètò ìdìbò, ní kété ti àwọn ilé ìgbìmọ aṣòfin bá ti gbe aba naa dé ìwáju rẹ̀.
Shittu fi kún pé, èyí yóò túbọ ràn ìlànà ètò ìdìbò Nàìjíríà lọ́wọ́ síí ni.








