Onísòwò ẹ̀jẹ̀: N2000 ni mò ń ra ẹ̀jẹ̀, N7000 ni mò ń tàá

Píǹtì ẹ̀jẹ̀
Àkọlé àwòrán, Achegbulu Paul tó jẹ́ ẹni ọdún márùndínláàdọ́ọ́ta ní òun ṣe owò yíì ní ilé oní yàrá kan ti òun ńgbé ní ìlú Èkó

Ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan tí jẹwọ́ pé òun ṣe kátàkárà ẹ̀jẹ̀ títà.

Ó ní òun máa n ra ẹ̀jẹ̀ ní owó pọ́ọ́kú lọ́wọ́ àwọn tó ń fi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, kí òun to fi owó lee láti tàá fún àwọn oníbàárà òun

Achegbulu Paul, tó jẹ́ ẹni ọdún márùndínláàdọ́ọ́ta ní, òun ṣe owò yíì ní inú ilé oní yàrá kan ti òun ńgbé ní ìlú Èkó.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí iléesẹ́ ọlọ́pàá fisíta sọ pé, òun máa ń fún àwọn tó bá wá fi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ni ẹgbẹ̀rún méjì náírà fun Panti ẹ̀jẹ̀ kan, tí òun máa ń tà ní ẹgbẹ̀rún méje náírà fáwọn ilé ìwòsàn.

Àtẹ̀jáde ọ̀hún sọ pe, àṣírí ọ̀rọ̀ ọ̀hún tú lẹ́yìn tí ọmọ ọdún mẹ́tàdílogun kan bá ara rẹ̀ ní ilé ìwòsàn lẹ̀yìn tí ó ti fi ẹ̀jẹ̀ pantì mẹ́rin sílẹ̀ láàárin ọjọ́ mẹ́fà, èyí ló mú kí ìyá rẹ̀ kíyèsíi pé nkan ò bójú mu bó ṣe ń gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀ lọ ilé-ìwé, tó sì ń fì bí òkú.

Lẹ́yìn tí ọlọ́pàá gbe ọgbẹ́ni Paul, tó jẹ́ àkọ́ṣẹmọṣẹ nípa àyẹ̀wò ara, ó jẹ́wọ́ pé ọ̀ún ti n ṣiṣẹ́ ọ̀hún láti ọdún márùn-ún sẹ́yìn.

Àwọn ọlọ́pàá ní àwọn tí bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti ríi dájú pé, àwọn ẹ̀jẹ̀ tó fí ń sọwọ́ sáwọn ilé ìwòsàn kò tíì ní ààrùn kankan nínú