Onímọ̀: Bí òbí bá ń mú sìgá, ọmọ rẹ̀ leè sàìsàn ọ̀nà ọ̀fun lọ́jọ́ iwájú

Siga

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbalagba ti ki i mu siga n bẹ ninu ewu lati ku iku ojiji nitori aisan ọna ọfun, ti iru ẹni bẹ ba dagba lọdọ obi to n mu siga.

Iwadi kan nilẹ Amẹrika lo fi idi eyi mulẹ.

Awọn to ṣe iwadi naa sọ pe, bi awọn ọmọde se n fa eefin siga simu ṣeeṣe 'ko fi kun iye awọn eeyan ti ki i mu siga, ṣe n ku l'ọdọọdun.'

Ajọ to n polongo tako aisan jẹjẹrẹ nilẹ Amẹrika lo ṣe agbatẹrun iwadi naa, laarin ọkunrin ati obinrin ti ki i fa siga, ti wọn to ẹgbẹrun lọna okoolelẹẹdẹgbẹrin o din mẹwaa. (710,000 )

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Sunday Adelaja: Tẹ́tẹ́ làwọn pásítọ̀ tó ń gba owó ‘ìserere’ ń ta

Àwọn onimọ sọ pe, ọna kan ṣoṣo lati daabo bo àwọn ọmọde ni lati dẹkun siga mimu.

Iwadi naa fihan pe, bi wọn ba fa eefin siga simu ju wakati mẹwa lọ lọsọọsẹ, o ṣeeṣe ki wọn ni aisan ọkan, rọpa-rọsẹ, to fi mọ aisan ọna ọfun.

Ninu iwadi naa ni wọn ti beere lọwọ awọn ti wọn fi ọrọ wa l'ẹnu wo, lori ibaṣepọ ti wọn ni pẹlu awọn to n fa siga lati kekere wọn, wọn si lo idahun awọn eniyan naa lati tọpinpin bi eto ilera wọn yoo ṣe ri ni ọdun mejilelogun si asiko yii.

Iwadi naa fihan pe, ijamba ti awọn ọmọde ti obi wọn n fa siga ba fi ori ko, lati igba ti wọn wa ni kekere yoo ba wọn dagba, ti yoo si fa aisan ninu ọpa to n gbe eemi jade.

Awọn oluwadi naa tun fi kun un pe, o tun le sọ iru awọn ọmọ bẹẹ di ẹni ti yoo fi aisan l'ogba nigba ti wọn ba d'arugbo.

Awọn onimọ ti wa sọ pe, ọna kan ṣoṣo lati doola ẹmi awọn ọmọde lọwọ aisan lọjọ iwaju, ni kawọn obi wọn dẹkun siga fifa.

Amuku siga

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn onimọ sọ pe ọna kan ṣoṣo lati daabo bo àwọn ọmọde ni lati dẹkun siga mimu.