Kwara: Ọti tita ati rira di eewọ nilu Ilọrin

Ọti to wa ninu igo ti wọn to sara ogiri

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọ ipinlẹ lo ti se ofin Sharia to tako ọti mimu ni Naijiria

Ijọba ipinlẹ Kwara ti fọwọsi ofin kan eyi to tako asa ọti rira ati tita nipinlẹ naa.

Gomina Abdulfatai Ahmed lohun si ofin yii ofin to tako ọti tita ati rira nigboro ilu Ilọrin lọjọ isẹgun lẹyin tile asofin ipinlẹ naa ti buwọlu abadofin ọhun.

Labẹ ofin yii, wọn ko ni gba ẹnikẹni laaye lati maa se ọti lile ta tabi maa taa loju taye tabi ki wọn maa mu ọti laarin igboro lawọn agbegbe kan nigboro ilu Ilọrin.

Gẹgẹbi ofin naa ti wi, ẹnikẹni to ba tapa si ofin naa yoo san owo itanran ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira tabi ko fi ẹwọn osu mẹfa jura.