Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ nìkan ló le tan ìṣòro ààbò, àwọn gómìnà 19 bọ́hùn

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Àwọn gómìnà mọ́kàndínlógún ẹkùn árìwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti àwọn ọba alayé ọrùn ìlẹ̀kẹ̀ ní ẹkùn náà ti pè fún àtúnṣe sí ìwé òfin orílẹ̀ èdè yìí.
Àyípadà kan gbòógì tí wọ́n ń bèèrè ni fífi àyè gba ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀.
Wọ́n ní èyí jẹ́ ọ̀nà kan gbòógì láti wá ojútùú sí ìpèníjà tó ń kojú ètò ààbò tó ń bá orílẹ̀ èdè yìí pàápàá ẹkùn náà fínra.
Wọ́n ní lára àwọn ìpèníjà tó ń bá ẹkùn náà fínra ni ìjínigbé, ìgbéṣùmọ̀mí, àwọn agbébọn àti àwọn ìpèníjà mìíràn.
Èyí ló jẹ́ àbájáde ìpàdé tí ẹgbẹ́ àwọn gómínà ẹkùn árìwá (NGF) àti ìgbìmọ̀ àwọn lọ́balọ́ba ẹkùn árìwá (NTRC) ṣe ní ọjọ́ Ajé ní ìlú Abuja.
Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí àwọn ẹgbẹ́ méjéèjì yìí yóò máa fẹnukò lórí pípè fún ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀.
Àwọn gómìnà àti àwọn olórí ẹgbẹ́ òṣèlú ní ẹkùn gúúsù ni wọ́n ti ń ṣaájú pè fún ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ṣùgbọ́n àwọn kàn lòdì sí ìpè náà.
Àwọn tó lòdì sí ìpe náà ní ó ṣeéṣe kí àwọn gómìnà ọ̀hún lò wọ́n fún àwọn ohun tí kò yẹ nítorí àwọn ló ń san owó oṣù fún wọn.















