Thomas Partey, agbábọ́ọ̀lù Arsenal tẹ́lẹ̀ di èèrò ilé ẹjọ́ nítorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn ti fi ẹsun ifipabanilopọ kan agbabọọlu fun Arsenal nigba kan, Thomas Partey.
Ẹsun ọhun to pin si ọna marun un ni wọn lo waye laarin ọdun 2021 si 2022, gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ.
Awọn obinrin mẹta lo fi ẹsun ọhun kan Partey - obinrin akọkọ fi ẹsun meji to ni i ṣe pẹlu ifipabanilopọ kan an, obinrin keji fi ẹsun mẹta kan an lori ọrọ kan naa, nigba ti obinrin kẹta fi ẹsun ẹyọkan ṣoṣo kan.
Agbabọọlu ọhun to jẹ ọmọ orilẹede Ghana sọ pe, oun ko jẹbi eyikeyi ẹsun ti wọn fi kan oun, ati pe tọwọtẹsẹ ni oun fi gba "anfaani lati fọ orukọ oun mọ".
Ọjọ Aje to kọja ni ẹni ọdun mejilelọgbọn ọhun pari iṣẹ rẹ pẹlu Arsenal, lẹyin to ti gba bọọlu fun wọn lati ọdun 2020.
BBC News ti kan si Arsenal, ajọ bọọlu, ati awọn alaṣẹ Premier League, lori ọrọ naa.
Awọn ẹsun naa jẹyọ lẹyin ti awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣe iwadii lati oṣu Keji ọdun 2022 ti awọn ọlọpaa kọkọ gba iwe ifisun lori ifipabanilopọ.
Ẹni to dari ikọ iwadii naa, Andy Furphy, sọ pe oun to jẹ awọn logun ni pipese atilẹyin fun awọn obinrin to ti yọju lati jẹrii lori awọn ẹsun ọhun.
"Ao rọ ẹnikẹni to ba ni ohunkohun lati ṣe pẹlu ẹjọ yii, tabi to ni awọn nnkan to le ran wa lọwọ, lati yọju si wa."
Ọjọ karun un oṣu Kẹjọ ni Partey yoo yọju sile ẹjọ Majisireeti to wa ni Westminster.
Ninu atẹjade kan ti agbẹjọro rẹ, Jenny Wiltshire fi sita lo ti sọ pe "Thomas Partey sọ pe oun ko jẹbi ẹsun kankan.
"Fun ọdun mẹta lo fi fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọlọpaa ati awọn ọtẹlẹmuyẹ lasiko iwadii wọn.
"O si ti ṣetan lati wi awijare rẹ."
Bakan naa ni agbẹjọro naa sọ pe onibaara oun ko ni le sọrọ lori awọn ẹsun naa nitori pe o ti di ọrọ ile ẹjọ.
Ọdun 2020 ni Thomas Partey kuro ni Atletico Madrid, to si darapọ mọ Arsenal pẹlu £45.3m ninu oṣu Kẹwaa ọdun 2020,
Igba marundinlogoji lo kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ fun wọn, o si gba bọọlu sinu awọn ni igba mẹrin.
Partey farahan ni idije Champions League ni igba mejila.
Yatọ si Arsenal. Partey tun n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Ghana, Black Stars.












