Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí ilé aṣòfin pé Natasha Akpoti-Uduaghan padà sẹ́nu iṣẹ́ rẹ́ gẹ́gẹ́ bíi aṣòfin

Oríṣun àwòrán, Natasha H Akpoti
Ile ijọ giga kan niluu Abuja ti paṣẹ pe ki wọn da Sẹnetọ to n ṣoju aringbungbun ipinlẹ Kogi, Natasha Akpoti-Uduaghan, pada sẹnu iṣẹ rẹ lẹyin ti ile aṣofin naa ni ko lo rọọkun nile fun oṣu mẹfa gbako.
Nigba to n gbe idajọ naa kalẹ, Onidajọ Binta Nyako sọ pe oṣu mẹfa ti wọn ni ko lọ rọọkun nile ti pọju
Nyako ni gẹgẹ bii abala 14(2) ofin to sọ nipa anfaani awọn aṣofin ṣe sọ, ijiya ti wọn fun aṣofin naa ko tọ ọ.
Adajọ ọhun fi kun pe ko tọ ki ẹkun idibo ti Natasha n ṣoju wa lai ni aṣoju kankan nile igbimọ aṣofin Naijiria.
Ẹwẹ, ile ẹjọ ọhun sọ pe Natasha jẹbi titapa si ofin ile ẹjọ nitori bo ṣe fi Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio ṣere lasiko to bẹ ẹ loju opo Facebook rẹ nigba ti igbẹjọ ọhun n lọ lọwọ.
Fun idi eyii, adajọ naa ni o gbọdọ san owo itanran ti iye rẹ jẹ miliọnu marun un naira fun ile ẹjọ.
Adajọ fi kun pe Natasha gbọdọ kọ iwe ẹbẹ loju opo Facebook rẹ ati ninu iwe iroyin meji ọtọọtọ to gbajumọ ni Naiiria.
O ni o gbọdọ ṣe gbogbo awọn nnkan wọnyii laarin ọjọ meje pere lẹyin idajọ naa.
Ki ni yoo ṣẹlẹ lẹyin idajọ yii?

Oríṣun àwòrán, Natasha H Akpoti
Agbẹjọro to ṣoju ile aṣofin, Paul Daudu SAN, sọ fun awọn akọroyin pe, awọn yoo ṣe agbeyẹwo iwe idajọ naa daadaa, ki awọn le mọ igbesẹ to kan lati gbe.
O ni "obiter dictum'' ni wọn n pe idajọ ti adajọ gbe kalẹ, eyi to tumọ si pe imọran tabi abaa lasan ni adajọ gba lori pe ọjọ ti wọn ni ki Sẹnetọ Akpoti fi joko sile ti pọ ju.
Ko ti i si ẹni to le sọ igbesẹ ti awọn agbẹjọro to ṣoju Akpoti-Uduaghan yoo gbe lẹyin idajọ. Idi ni pe, wọn kọ lati ba awọn akọroyin sọrọ .
Amọ ṣa, akọroyin BBC sọ pe oju wọn kọrẹ lọwọ lẹyin idajọ naa.
Ohun to ṣẹlẹ sẹyin
Ninu oṣu Keji ọdun 2025 ni ede aiyede ṣẹlẹ ni ile aṣofin agba Naijiria, laarin Aarẹ ile naa, Sẹnetọ Godswill Akpabio ati Sẹnetọ Natasha Akpoti-Uduaghan.
Akpabio paṣẹ lasiko ti ijiroro n lọ pe, ki awọn oṣiṣẹ alaabo gbe e jade lẹyin ti obinrin naa kọ lati joko ni aaye tuntun ti wọn fun, to si sọ awọn ọrọ ibinu.
O fi ẹsun kan Akpabio pe o mọọmọ fẹ pa oun lẹnu mọ ni, to si fẹ gba anfaani ti oun ni lati da si ijiroro ile, lọwọ oun.
Lẹyin gbogbo awuyewuye to waye lọjọ naa, ile aṣofin fi ẹsun kan Natasha pe o tapa si awọn ilana ile naa, pẹlu bo ṣe kọ lati jokoo si aaye ti wọn fun un.
Ọrọ naa de iwaju igbimọ to n ba awọn aṣofin wi, ṣugbọn Natasha kuna lati farahan niwaju igbimọ naa.
Lẹyin rẹ ni wọn kede pe wọn ti da a duro fun oṣu mẹfa.
Ọrọ ọhun pada di ti ile ẹjọ, pẹlu bi igun mejeeji ṣe pe ẹjọ ọtọọtọ lori rẹ.















