Man Utd lulẹ̀, Arsenal fakọyọ nínú ìdíje UEFA Champions league

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lana ninu idije UEFA Champions League, ẹkọ o soju mumu fun ikọ Manchester United lẹin ti ọwọ iya Bayern Munich tẹ, ti wọn si dojuti wọn lorilẹede Germany.
Lernoy Sane, agbaọwọ iwaju fun Bayern lo kọkọ mi awọn ni isẹju mejidinlọgbọn, Gnabry fi ọba le isẹju mejilelọgbọn, ti inu si bi Hojlund ti ikọ Man Utd to si da ẹyọ kan pada.
Ni saa keji, Harry Kane gba pẹnariti wọlẹ ni isẹgun mẹtalelaadọta.
Ikọ Manchester United fi ija si opin, ti Casemiro si mi awọn ni isẹju mejidinlaadọrun, eyi lo ba tun bi ikọ Bayern nini, ti wọn si tun fi ẹyọ kan si nigba Tel mi awọn ni isẹju mejilelaadọrun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Casemiro saa gbogbo ipa rẹ lati mi awọn kan si ni isẹju marundinlaadọrun sugbọn asọ ko ba ọmọyẹ mọ.
Amule ikọ Man Utd, Andre Onana ti ni ki awọn ọmọ Man Utd ma ṣe binu si oun nitori oun ni oun sokunfa bi ikọ Bayern ṣe fi iya jẹ wọn.
Bakan naa ikọ Arsenal pada si idije UEFA Champions League pẹlu ọna ara ti wọn si bu ifọti lu ikọ PSV Eindhoven pẹlu ami ayo mẹrin si odo.
Bukayo Saka lo sii de goolu naa, ti Trossard, Gabriel Jesus ati Odegaard fi fi ọba le.
Bi awọn ifẹsẹwọnsẹ yooku ṣe lọ ree
Real Madrid 1- 0 Union Berlin
Bayern Munich 4-3 Man Utd
Arsenal 4-0 PSV Eindhoven
Real Sociedad 1-1 Inter Milan
Galatasaray 2-2 FC Copenhagen
Sevilla 1-1 Lens
Sporting Braga 1-2 Napoli
Benfica 0-2 RB Salzburg
Feyenoord 2-0 Celtic
Lazio 1-1 Atlético Madrid
AC Milan 0-0 Newcastle United
Paris Saint Germain 2-0 Borussia Dortmund
Young Boys 1-3 RB Leipzig
Manchester City 3-1 Red Star Belgrade
Barcelona 5-0 Royal Antwerp
Shakhtar Donetsk 1-3 FC Porto












