Wo ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa ìlànà ìtọ́jú 'acupunture'
'A ti gba ìtọ́jú ‘acupuncture’, ó sì wò wá sàn'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin ti ile-iṣẹ iroyin BBC Yoruba bere boya awọn eniyan mọ nipa ilana fifi abẹrẹ ṣe itọju alaarẹ ni Naijiria, awọn eeyan kan ti jade lati jẹrii si bi ilana ọhun ṣe wo wọn san.
Arabinrin kan to pe orukọ ara rẹ ni Ọmọbabirin Adebukola Oluwaseyi-Kumuyi ṣe alaye fun BBC Yoruba bi ilana naa ṣe mu alaafia ba baba rẹ.
Adebukola wi pe “baba mi ko lee lo ẹya ara rẹ kankan mọ dipo pe gbogbo ile-iwosan olowo gọbọi to wa nilu Eko yii la gbee lọ.
Lori bi a ṣe n paara ile-iwosan ni ẹni kan sọ fun wa pe ki a maa gbee lọ ọdọ awọn to n fi abẹrẹ ṣe iwosan.
Lẹyin ọsẹ meji dokita yii bẹrẹ itọju baba mi, o ti lee lo ọwọ rẹ mejeeji bayi o si ti lee sọrọ.”
Ni ti arabinrin Tolulope Abioye, airi oyun ni lẹyin ọmọ kan ni idaamu to n gbee kiri ile-iwosan ati ọdọ awọn dokita to ṣerọju ẹya ara obirin.
Tolulope sọ fun BBC Yoruba pe awọn dokita ni ohun ko ni le bimọ mọ nitori ona abawọle ile ọmọ ohun ti fun pọ leyi ti ko nii jẹ ki ohun o lee loyun mọ.
“Ikọminu eyi lo mu ki n maa ṣe oniruuru ifimufinlẹ lori ẹrọ ayelujara ko too di pe mo ka nipa ‘acupuncture’.
"Bi mo ṣe kaa ti mo si ri pe o le wo ailera mi san ni mo wa awọn oniṣegun rẹ kan nilu Eko.
"Lẹyin bi oṣu kan ti mo bẹrẹ itọju yii ni ayipada de ba ilera mi ti mo si bẹrẹ si nii ṣe awọn nkan ti mi o le ṣe tẹlẹ.
"Mo dupẹ pe mo ṣe alabapade ilana itọju yii.”
Fun ọmọba Gbenga Lufadeju to jẹ ololufẹ ere idaraya ẹyin ori ọdan ti a mọ si ‘Lawn Tennis’, ilana itọju yii lo jẹ ohun manigbagbe.
Ọmọba Lufadeju wi pe ohun ko lee kopa daadaa mọ ninu awọn ere idaraya ti ohun nifẹ si ti ohun si ti na ọpọlọpọ owo lati lee ri iwosan.
“Nigba ti mo gbọ nipa ‘acupuncture’, mo kan tun fẹẹ gbiyanju ẹ wo ni amọ modupẹ pe mo gbe igbesẹ naa.
Ni bayi, mo le gba ‘lawn tennis’, ‘golf’, mo si tun n sun daadaa ju ti atẹyinwa lọ.
Mi o lo ogun kankan bẹẹ ni nko ṣiṣẹ abẹ, abẹrẹ nikan naa ni wọn fi n ṣe itọju mi to si bami lara mu.
Mo rọ ijọba lati gbaruku ti ilana yii kawọn eeyan lee nimọ kikun nipa rẹ.”
Kíni ìjọba n ṣe nípa àwọn tó n ṣe ‘acupuncture’?
Ninu ifọrọwerọ pẹlu Adenike Onanuga to jẹ igbakeji adari ni ajọ to n moju to iṣegun ibilẹ nipinlẹ Eko, o ṣe alaye fun BBC Yoruba pe ijọba ipinlẹ Eko ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu awọn oniṣegun ibilẹ lapapọ leyi to mu ki wọn ṣe agbekalẹ ajọ ti yoo maa ṣabojuto wọn.
Onanuga wi pe ijọba ti bẹrẹ si nii fun awọn oniṣegun ‘acupuncture’ niwe ẹri idanimọ lati fihan pe wọn gba oore-ọfẹ ijọba.
O wi pe ijọba ṣe eyi lati jẹ kawọn araalu o da ojulowo awọn oniṣegun naa mọ yatọ si awọn ayederu.
Onanuga fi kun pe ijọba ṣi n kesi awọn to ku sita lati waa forukọ silẹ pẹlu ijọba ki wọn lee gba iwe ẹri lẹyin ti ijọba ba ti rii pe wọn kunju oṣuwọn.
Kí ni ohun tí o mọ̀ nípa ìlànà ìtọ́jú fífi abẹ́rẹ́ ṣe ìwòsàn?

Fifi abẹrẹ ṣe iwosan, ti a mọ si ‘acupuncture’, lo jẹ ilana itọju aisan to bẹrẹ lati orilẹ-ede China lati ọjọ pipẹ.
Ilana itọju yii ni awọn oniṣegun rẹ maa n ti awọn abẹrẹ tiirin bọ inu ara lawọn aaye to lapẹẹrẹ lati mu ki ilera o ba alaisan ti wọn n tọju.
Nigba miran, ilana yii ni wọn maa n tunṣe lẹyin ọjọ diẹ ki alaafia pipe o too de ba onitọhun.
Njẹ́ ìlànà ìtọ́jú yìí tiẹ̀ wà ní Nàìjíríà?

Bo tilẹ jẹ pe ilana yii ko fi bẹẹ gbajumọ ni Naijiria, awọn kan naa wa ti wọn ṣe iṣẹ yii ti wọn si nigbagbọ ninu rẹ lati ṣe iwosan pipe fun alaarẹ.
Dokita Edison Christian to jẹ alaga awọn oniṣegun Acupuncture ni Najiria wipe wọn ko pọ ni tootọ amọ wọn n gbiyanju lati jẹ ki gbogbo araalu o mọ nipa rẹ.
Edison to dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Eko fun atilẹyin rẹ fun awọn oniṣegun acupuncture rọ ijọba apapọ lati tẹwọ gba ilana itọju naa gẹgẹ bi ajọ UNESCO ati WHO ṣe tẹwọ gba a.
Ọjọgbọn Adebukunola Adefule-Oshitelu to sọrọ nibi isami ayajọ ti UNESCO ya sọtọ fun iwosan pẹlu abẹrẹ wipe Olodumare ti fun olukuluku ni ohun to lee ṣe iwosan lagbegbe wọn.
Ọjọgbọn naa wi pe bo tilẹ jẹ pe oju tawọn kan fin n wo ohun to nii ṣe pẹlu itọju nilana ibilẹ ni pe ko wuyi to, lilo abẹrẹ fun itọju alaarẹ ni o jẹ itẹwọgba kaakiri aye.
“Oriṣiriṣi anfani lo wa ninu ‘acupuncture’ to fi mọ itọju lai lo oogun tabi ṣiṣẹ abẹ.”
Adefule-Oshitelu waa rọ ijọba lati ṣe iranwọ nipa atankalẹ ilana iwosan ọhun.















