Kọ́lẹ́rà bẹ́ sílẹ̀ l‘Eko, èèyàn márùn-ún kú, ọgọ́ta wà ní ilé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, Ministry of Health
Kò dín ní èèyàn márùn-ún tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn bí àìsàn onígbáméjì ṣe bẹ́ sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko.
Kọmíṣọ́nà fún ètò ìlera, Ọ̀jọ̀gbọ́n Akin Abayomi tó kéde ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ọgọ́ta míì tún wà ní ilé ìwòsàn tí wọ́n ń gba ìtọ́jú.
Abayomi ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Eti-Osa, Lagos Island, Ikorodu àti Kosofe ni àìsàn náà ti gbilẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé ìjọba ti ń gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti tètè kojú ìṣòrò náà, tó sì rọ àwọn ará ìlú láti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọrí, kí wọ́n má tan àìsàn náà kalẹ̀ jú bó ṣe yẹ lọ.
Ó fi kun pé ẹ̀ka tó ń mójútó àyíká lábẹ́ iléeṣẹ́ ètò ìlera ìpínlẹ̀ Eko ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti mọ omi ní agbègbè Lekki sí Victoria Island láti mọ ohun tó ṣokùnfà àjàkálẹ̀ àìsàn náà.
“A fura pé àìsàn onígbáméjì ló bẹ́ sílẹ̀, a ti bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò àti ìwádìí lórí rẹ̀. Ní oṣù Kẹrin ọdún 2024, Nàìjíríà ní àkọ́ọ́lẹ̀ àìsàn onígbáméjì ní ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n, tí èèyàn mẹ́rìnlá sì ba lọ.
Ó tẹ̀síwájú pé látàrí òjò tó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rọ̀ báyìí, àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rí àwọn aláìsàn tí wọ́n ń bí, tí wọ́n sì ń yàgbẹ́ gbuuru.

"Mímu omi iyọ̀ àti ṣúgà láti ri pé omi kò tán lára ẹni tó bá ní àìsàn Kọ́lẹ́rà jẹ́ ọ̀nà láti ṣe ìtọ́jú àìsàn ọ̀hún"
Ọ̀jọ̀gbọ́n Akin Abayomi ní àwọn àdúgbò tí èrò pọ̀ sí àtàwọn tí àyíká wọn kìí mọ́, ló wà nínú ewu tó lágbára jùlọ.
Kọmíṣọ́nà náà ṣàlàyé pé, àìsàn onígbáméjì jẹ́ èyí tó máa ń sáré tàn kalẹ, tó máa ń fa ìgbẹ́ gbuuru, tó sì lè sáré mú ẹ̀mí lọ, tó lè ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tí wọn ko bá tètè mójúto.
Àìsàn onígbáméjì máa ń tàn nígbà tí èèyàn bá jẹ oúnjẹ tàbí mu omi tí kòkòrò àìsàn náà bá wà.
Bákan náà ni àìsàn onígbáméjì le tàn tí kò bá sí ìmójútó àyíká tó péye, tí èèyàn kò bá fọ ọwọ́ rẹ̀ dáadáa.
Lára àwọn àmì àpẹẹrẹ àìsàn onígbáméjì ni ìgbẹ́ gbuuru, èébì, kí omi sáré tán ní àgọ́ ara, ara gbígbóná, kí èèyàn ṣàdédé ṣubú lulẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Gẹ́gẹ́ bí Abayomi ṣe wí, mímu omi iyọ̀ àti ṣúgà láti ri pé omi kò tán lára ẹni tó bá ní àìsàn náà jẹ́ ojúná láti ṣe ìtọ́jú àìsàn ọ̀hún.
Bákan náà ló rọ àwọn ará ìlú láti ri dájú pé wọ́n máa ń mu omi tó mọ́, kí wọ́n sì yé lo omi ìdọ́tí láti dènà àìsàn onígbáméjì.
Ó ní kí àwọn jìnà sí yíya ìgbẹ́ ní gbangba kí wọ́n sì máa ṣe ìtajú ilé ìgbọ̀nsẹ̀ wọn dáadáa láti dènà àìsàn onígbáméjì.
“A rọ àwọn èèyàn láti máa fọ ọwọ́ wọn ṣaájú kí wọ́n tó jẹun àti lẹ́yìn tí wọ́n bá kúrò nílé ìgbọ̀nsẹ̀ láti dènà àwọn àrùn bíi onígbáméjì yìí.”
Ó sọ àrídájú rẹ̀ pé iléeṣẹ́ ètò ìlera ìpínlẹ̀ Eko, àjọ tó ń mójútó àjàkálẹ̀ àrùn, NCDC àtàwọn iléeṣẹ́ ètò ìlera mìíràn ń ṣiṣẹ́ láti mójútó ìdènà ìtànkálẹ̀ àìsàn náà.















