Ó kéré tán ènìyàn 15,000 ló ti sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀ ní Mozambique
Mozambique: Ajọ IOM ni ibẹru ki awọn agbesunmomi alakatakiti ẹsin Musulumi ma tun wa ṣe ikọlu si wọn lo mu wọn sa kuro ni agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, AFP
O kere tan eniyan ẹgbẹrun marundinlogun lo ti sa asala kuro ni agbegbe Cabo Delgado, lorilẹede Mozambique
Ajọ to n risi irinkerindo awọn eniyan, International Organization for Migration (IOM) lo fi iroyin naa lede.
Ikọlu naa bẹrẹ ni nkan bi ọsẹ kan sẹyin ni Guusu ariwa agbegbe ti wọn ro wi pe ko ni iṣoro tẹlẹ.
Ọdun 2017 ni ogun bẹ silẹ ni agbegbe naa, ti eniyan to le ni ẹgbẹrun mẹrin si ti ku, ti eniyan to le ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin si tisa asala fun ẹmi wọn kuro ninu ile wọn.
Ajọ IOM ni ibẹru ki awọn agbesunmomi alakatakiti ẹsin Musulumi ma tun wa ṣe ikọlu si wọn lo mu wọn sa kuro ni agbegbe naa.
Wọn ni awọn ọmọde wa ninu awọn to sa asala fun ẹmi wọn, ti aboyun to le ni marundinlaadoje si wa laarin wọn.
O ṣeeṣe ko jẹ pe awọn wọnyii n sa asala fun ẹmi wọn fun igba keji, lẹyin ti wọn kuro ni agbegbe ti wọn wa tẹlẹ nitori ogun ohun.
Bio tilẹ jepe ijọba n kesi awọn eniyan lati pada si ile wọn, amọ ajọ IOM ni awọn eniyan to ba wu ni yoo pada kii ṣe ki ijọba maa kan ni pa fun wọn.












