Ọmọ ààrẹ Mozambique tẹ́lẹ̀, rí ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlá he fún kíkó ìlú sí àdánwò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile ẹjọ ti ju ọmọ arẹ orilẹ-ede Mozambique nigba kan, si ẹwọn ọdun mejila fun ẹsun pe o na $2.2bn owo ilu sori okoowo ẹja kan to ko orilẹ-ede naa si adanwo ọrọ aje.
Ndambi Guebuza, ọmọ aarẹ Armando Guebuza, wa lara eeyan mọkanla ti wọn lo jẹbi kiko owo jẹ ati kio owo pamọ lọna aitọ.
Aarẹ Guebuza kuro ni ipo lọdun 2015, lẹyin ọdun mẹwaa.
Onidajọ Efigenio Baptista sọ pe Ndambi Guebuza fi owo naa gbọ bukaata igbe aye ajẹrọrun.
Awọn mii ti wọn tun ju si ẹwọn ni Gregorio Leao, olori ileeṣẹ alaabo ọtẹlẹmuyẹ, Antonio do Rosario, to pada di olori ileeṣẹ mẹta kan ti ijọba da silẹ.
Orukọ awọn ileeṣẹ naa ni wọn fi ya owo.
Adajọ sọ pe o sẹni laanu pe awọn to yẹ ko jẹ awokọṣe rere, gan-an lo n ba ilu jẹ́.
Laarin ọdun 2013 si 2014 ni ileeṣẹ mẹta ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ, ya owo to le ni biliọnu meji Dọla ($2.2bn).
Pupọ ninu rẹ ni wọn ko gba aṣẹ tabi ontẹ lọwọ ile aṣofin ti wọn fi ya wọn.
Ijọba Mozambique lo si ṣe oniduro wọn, eyi to tumọ si pe ijọba ni yoo san gbese naa pada, ti nkan ba fi yíwọ́.
Wọn ni awọn fi owo naa ra ileeṣẹ ẹja kan, ọkọ oju omi fun eto aabo, ati lati gbọ bukaata awọn nkan mii to nii ṣe pẹlu awọn ileeṣẹ ti ijọba ti ní ipin idokowo.
Gbogbo eyi ni wọn ṣe lasiko ti Armando Guebuza fi wa ni ipo aarẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọdun 2016 ni ipa gbese naa bẹrẹ si ni han lara ọrọ aje orilẹ-ede Mozambique.
O fa ọwọ gogo ounjẹ ati awọn nkan mii, eyi to mu ki igbe aye nira fun araalu.
Awọn oluyẹ iwe owo wo tun sọ pe ẹẹdẹgbẹta miliọnu tun poora lara owo naa.
Ile ifowopamọ Credit Suisse ati VTB to jẹ ti Russia, lo ya wọn ni owo naa.
Mẹta lara awọn oṣiṣẹ Credit Suisse si lo lọ si ẹwọn ni America fun ẹsun kiko owo pamọ lọna aitọ, nitori gbese naa.
Lọdun to kọja, ijọba UK ni ki banki naa san $178m, owo itanran nitori ẹsun òwò ẹja naa.
Bakan naa ni wọn tun paṣẹ fun banki naa pe ko wọgile igba miliọnu Dọla ($200m) ninu gbese naa ti Mozambique jẹ, nitori pe iwa ibajẹ ni wọn fi ya a.












